Aburo wa lawọn eeyan orile-ede Niger, ko yẹ ka doju ogun kọ wọn – El-Zakzaki

Adewale Adeoye

Olori ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Islamic Movement Of Nigeria’ (IMN), Sheikh Ibrahim El-Zakzaky, ti rọ olori orile-ede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lati ma ṣe lo ọwọ agbara, tabi ko ikọ ṣọja orile-ede wa lọọ kogun ja awọn eeyan orile-ede Niger rara, o ni aburo lawọn eeyan naa jẹ si wa.

El-Zakzaky sọrọ ọhun di mimọ lakooko tawọn onimọ kewu kan lọọ ki i nile rẹ to wa niluu Abuja laipẹ yii.

Ninu ọrọ rẹ lo ti naka abuku sawọn alaṣẹ orile-ede Amẹrika ati ilẹ Faranse pe awọn gan-an leku ẹda ti wọn n fẹ fori orile-ede wa Naijiria gba tilẹ Niger, nipa bi wọn ṣe n yin sọrọ naa labẹnu, ti gbogbo nnkan si fẹẹ daru patapata bayii.

‘ Ẹni ti ko mọ ni ko mọ, lojiji lawọn alaṣẹ orile-ede Amẹrika ati tilẹ Faranse fẹẹ lo orile-ede Naijiria lati koju ogun si ilẹ Niger, bẹ kẹ, ọmọ iya kan naa lawa mejeeji jẹ ni gbogbo ọna. Awọn ẹya Guusu le ma mọ eyi pe ọkan lawa mejeeji jẹ, ṣugbọn awa ta a wa lapa Oke-Ọya nibi mọ daadaa pe ọmọ iya wa lawọn araalu orile-ede Niger. Ko si ba a ṣe maa ṣe e ti itan ko ni i so wa pọ, awọn baba nla wa kọọkan jẹ ibatan silẹ naa.

Ba a ba si ni ka wo o nipa aṣa naa, ko fi bẹ si iyatọ kan lọ titi laarin awa mejeeji rara, ẹlẹgbẹ pe ibeji lati ọrun wa ni awa mejeeji jẹ, ta a si paala sẹgbẹẹ ara wa.

Mo si n gbọ ahesọ pe awọn soja Naijiria fẹ lọọ kogun ja awọn orile-ede Niger, Ọlọrun ko ni i jẹ ki eyi waye rara. Ohun ti mo mọ to da mi loju daadaa ni pe awọn alagbara kan ni wọn fẹẹ fori orile-ede wa gba tawọn orile-ede Niger yii. Inu okunkun ni wọn wa, ti wọn si n tafa sinu imọlẹ, awọn gan-an ni wọn n ti awọn olori wa pe ka lọ kogun ja wọn. A ko ni i doju ogun kọ awọn to jẹ aburo wa, ka waa maa gbẹmi wọn, eyi ki i ṣohun to daa rara. Bi wọn ṣe maa n ṣe niyẹn. Wọn ti ṣe bẹẹ fawọn araalu orileede Iran ati Iraq tẹlẹ.

Leave a Reply