Mi o ni i ja Aarẹ Tinubu atawọn aṣofin orile-ede yii kulẹ – Keyamo

Adewale Adeoye

Ọkan lara awọn minisita ti wọn maa ba Olori orile-ede yii,  Bola Ahmed Tinubu, ṣiṣẹ pọ ninu iṣakoso ijọba rẹ, Ọgbẹni Festus Keyamo, ti ṣeleri pe oun ko ni i ja Aarẹ naa atawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja kulẹ lori ipo minisita ti wọn fẹẹ yan oun si.

Keyamo to n ṣoju ipinlẹ Delta, sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii niluu Abuja, lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin tawọn aṣofin ti fontẹ lu u pe o yege ninu ayẹwo ti wọn ṣe fun un.

Keyamo to ti figba kan jẹ minisita ninu ijọba Buhari tẹlẹ dupẹ gidi lọwọ awọn aṣofin agba ọhun lori bi wọn ṣe fimọ ṣọkan, ti wọn si fontẹ lu orukọ rẹ pe o yege lati dipo minisita mu ninu iṣakoso ijọba  Tinubu.

‘Ọpẹ ni ma a du fawọn aṣofin ti wọn ka mi yẹ, ti wọn si sọ pe mo yege. Mo tun maa dupẹ gidi lọwọ Aarẹ Tinubu naa lori bo ṣe pe mi sinu iṣakooso ijọba rẹ lati ṣiṣẹ fun un, ati orile-ede Naijiria lapapọ.

‘Mi o mọ bi ma a ṣe dupẹ naa to fohun ti wọn ṣe fun mi yii, bi mo ba bẹrẹ si i dupẹ lataarọ, ko to rara, emi paapaa si ti ṣeleri bayii pe mi o ni i ja wọn kulẹ lagbara Ọlọrun Ọba.

‘Ko si baa ṣe fẹẹ rin tori ko ni i mi, beeyan ba n ja fẹtọọ awọn araalu, o gbọdọ ro gbogbo rẹ papọ daadaa ni, bo o ba faake kọri pe afi dandan ki ohun gbogbo lọ ni ilana tiẹ, ti oo gba sawọn iyooku lẹnu. Awọn araalu to n ja fun gan-an ni wọn maa jiya rẹ lopin ohun gbogbo.

Idi ree ti mo fi n dupẹ lọwọ awọn aṣofin agba ọhun ati Aarẹ Tinubu lori ipa ti wọn ko ki n le di minisita ninu iṣakoso ijọba to wa lode bayii.

Leave a Reply