Jamiu Abayọmi
Ẹgbẹ ile-iwe aladani, National Association of Proprietors of Private Schools(NAPPS), labẹ Aarẹ ẹgbẹ naa, Abayọmi Otubẹla, ti sọ pe nitori ọwọngogo epo bẹntiroolu to gbode kan bayii, ọpọlọpọ ile-iwe lo maa pa lilo ọkọ bọọsi lati fi ko awọn ọmọ ti, ki awọn obi wa ọna miiran ti wọn yoo maa gba fi gbe ọmọ wọn dele-iwe, o si tun ṣee ṣe ki afikun de ba owo ile-iwe awọn ọmọ wọn.
Otubẹla sọrọ ọhun di mimọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ sẹkitariati, gbọgan ipade ati ile-igbe fun ẹgbẹ wọn niluu Abuja.
O ni, “Asiko yii jẹ eyi ti idojukọ to lagbara n koju gbogbo ẹka, ti awa ileewe aladaani naa ko gbẹyin, idi niyi ta a ṣe ke si awon akọṣẹmọṣẹ lati forikori, ti a si tun fikunlukun pẹlu wọn lati wa ọna abayọ si bi awa naa yoo ṣe duro ṣinṣin.
“Nibi ipade ti a ṣe ni a ti gbero lati din gbogbo nnkan ti o n muwa nawo, ti ko ni i ṣe pupọ pẹlu awọn ohun to wa ninu korikulọọmu wa ku, ki a si gbaju mọ awọn ohun to maa mu itẹsiwaju ba eto ẹkọ awon ọmọ nikan. Bakan naa la tun ti sọ fun awọn ileewe lati pese ilegbee fun awọn olukọ wọn, ki eyi le din owo mọtọ ti wọn n naa lojoojumọ ku.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn maa ṣe afikun sowo awọn olukọ naa, ṣugbọn ki eyi baa le wa si imuṣẹ, owo ileewe awọn ọmọ yoo le kun, ati awọn nnkan mi-in ti ile-iwe n pese, o waa ni ki awọn obi ati alagbatọ maa mura silẹ lati san alekun owo.
“Awa naa mọ pe igbesẹ wa yii yoo ni awọn obi lara diẹ, nitori ọpọlọpọ awọn ile-iwe wa gbogbo ni wọn ti pa owo fifi bọọsi gbe awọn akẹkọọ ti, nitori pe gbese ni wọn n jẹ nidii ẹ. Ohun ti mo ro pe awọn obi le ṣe ni ki wọn jẹ ki awọn ọmọ wọn maa gbe nileewe (Hostel), tabi ki wọn wa ọna abayọ mi-in, ṣugbọn a n rawọ ẹbẹ si ijọba lati ya wa lowo ti ele ori ẹ ko ni i pọ.
“A ti gba ijọba nimọran lati da banki eto ẹkọ silẹ, leyii ti yoo jẹ ko rọrun fun gbogbo awọn to ni nnkan ṣe pẹlu eto ẹkọ lati le yawo nibẹ, ki wọn le ri nnkan lo fun idagbasoke ara wọn ati ile-ẹkọ”
Ọgbẹni Abayọmi sọ siwaju pe awọn ileewe aladaani nilo iranlọwọ ki wọn le duro daadaa si i.
“Ọpọlọpọ ni ko mọ pe inu gbese nla ni awọn ile-iwe wa maa n wa, bẹẹ naa si ni a kan n ṣe iṣẹ idasilẹ ileewe bii ajọ alaaanu fawọn araalu ni, lai si ere kankan nibẹ”.