Aṣọ ni mo lọọ ra fawọn ọmọ mi ni Lekki ti won fi lu wa lalubami-Portable 

Monisọla Saka

Gbajumọ ọkunrin olorin taka-sufee tawọn ọdọ asiko yii fẹran gan-an, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazuu Zeh, ti ke gbajare lori bi awọn eeyan ṣe ṣe oun atawọn ọmọ ẹyin ẹ leṣe lagbegbe Lekki, nipinlẹ Eko.

Lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni Portable gbe fidio loriṣiiriṣii sori opo Instagram rẹ, nibi to ti n ṣalaye bọrọ ṣe jẹ.

O ni ile itaja igbalode ti wọn ti n ta aṣọ loun ko awọn ọmọ abẹ oun lọ lati le raṣọ fun wọn, lojiji lawọn eeyan kan ya de, ni wọn ko lilu gidi foun atawọn ọmọ oun, wọn lu wọn gidigidi debii pe oju ọkan ninu wọn ti wọn n pe ni Young Duu bẹ, oju egbo naa si jin wọnu. Bakan naa ni oju ọkunrin naa daranjẹ, eyi lo mu ki Portable binu sọrọ pe awọn ara Lekki ti ṣe tiwọn, o ni eyi to ba ṣeeṣi de adugbo toun naa ni Sango, ko ni i jade kuro nibẹ laaye.

Pẹlu omi loju, ni Portable fi n pariwo sọrọ ninu mọto toun pẹlu awọn ọmọ ẹyin ẹ ọhun wa, o ni, “Wọn ti ba oju awọn ọmọ mi jẹ o, ẹ wo oju ẹ, ẹyin naa ẹ wo o. Aṣọ ni mo gbe wọn jade lati ra fun wọn tawọn ẹni yẹn ya de lojiji o. Wọn lu wa, ẹ wo oju ọmọ mi, ẹ wo bi wọn ṣe ṣoju ẹ. Mi o ni i gba, ki wọn ma wa si Sango ni o, Aje wọn maa ku ni.

Bawọn kan ṣe n ba a daro lori ẹrọ ayelujara lawọn eeyan mi-in n bi i ni ibeere loriṣiriṣii. Bross ni o yẹ ki wọn fi Portable si Big Brother tawọn eeyan n wo, nitori ojumọ kan, àrà kan ni ọrọ Portable. Halcy ni tiẹ ba wọn wi ni, o ni eyi ti wọn fi n rojọ sinu fidio yii, ṣebi niṣe lo yẹ ki Portable kọkọ sare gbe ọkunrin to ṣeṣe  ọhun lọ sileewosan na, ko le baa tete ri itọju. Bayọ beere, o ni ṣe wọn fi wahala Lekki ṣe Portable ni, abi ki lo de to jẹ o ṣaa maa n kagbako ni Lekki ni. Ọrọ Dre ati Okito jọ ara wọn, wọn lawọn ro pe awọn ọmọ olowo ni wọn n gbe ni Lekki ni, pe kin ni nnkan naa ti yoo mu awọn ọmọ Lekki da ẹsẹ wọ Sango wa.

Bẹẹ lawọn eeyan mi-in n ki ọkunrin to maa n pe ara ẹ ni Ika of Afrika ọhun pẹlẹ, wọn ni búlóò ti wọn fun un loju yoo tubọ jẹ ko búlóò si i ni.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Portable fi mọto olowo nla rẹ lasidẹnti lagbegbe Lekki yii kan naa nipinlẹ Eko. Eyi lo jẹ ki ara tubọ maa ta a buruku buruku si i, tawọn eeyan si fi n beere nnkan ti oun ati Lekki atawọn eeyan ibẹ jọ da pọ.

 

Leave a Reply