Eyi ni bi ina ṣe jo ile adẹrin-in-poṣonu ilẹ wa yii gburugburu

 Jamiu Abayọmi

Gbajugbaja alawada, sọrọsọrọ ati oṣere ori-itage nni, Ayọdeji Richard Makun, ti ọpọ eeyan tun mọ si AY, ni ina nla kan sọ ninu ile rẹ to wa niluu Eko lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kefa, oṣu Kẹjọ, ọdun ti a wa  yii.

Ninu fọnran fidio kan to wa loju opo ayelujara nipa iṣẹlẹ naa lo ṣafihan ile-alaja meji ọkunrin naa to n jo, oke patapata ile naa lo si n jo ju.

Ọpọlọpọ dukia lo ṣofo ninu ile ohun pẹlu bi ina naa ṣe fẹju kẹkẹ, to si ran ile naa yika.

Ọpọlọpọ awọn gbajumọ bii tiẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn ti n  ba a kẹdun lori iṣẹlẹ naa, ti wọn n gbadura fun un kikankikan. Ohun to kọkọ ko ipaya ba awọn ololufẹ rẹ ni pe ṣe AY ko si ninu ile tabi awọn mọlẹbi rẹ kankan nile lasiko ti ijamba ina naa ṣẹlẹ.

Ọkunrin oṣere ori itage, to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ondo, naa lo gbe fidio kan si oju opo Insitagiraamu rẹ, nibi to ti ṣafihan pe alaafia ni oun ati awọn mọlẹbi oun wa. Oṣere yii gbe aworan tiẹ, ti iyawo rẹ ati tawọn ọmọ rẹ mejeeji si fidio ọhun.

Labẹ fidio ọhun lo ti kọ ọ sibẹ pe, “Ohun gbogbo to ba wa ni yoo pada, ẹbi ati Ọlọrun nikan lo ṣe pataki ju lọ laye, mi o le duro lati darapọ mọ yin l’Amẹrika laipẹ ọjọ”.

Bayii ni ọkunrin alawada yii ṣe kọ ọ sabẹ fidio yii lati fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe ko si nnkan to ṣe oun ati mọlẹbi oun, ti awọn eeyan si tun n ba a kẹdun, ti wọn tun n gbadura fun un pe Ọlọrun yoo da gbogbo ikolọ rẹ pada.

Leave a Reply