Jamiu Abayọmi
Ọkunrin kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ orukọ rẹ tabi ohun to ṣe e lo ṣadeede bẹ sodo ọsa lagbegbe Lẹkki-Ikoyi, niluu Eko, lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.
Awọn ẹṣọ alaabo ẹmi ati iṣẹlẹ pajawiri ti wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati doola ẹmi ẹni to ko sodo naa, bakan naa ni awọn ọlọpaa ti yi gbogbo agbegbe naa po.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni “Loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, awọn ọlọpaa oju omi, ati ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ yii naa si ti kan lumi lati wa aaye tabi oku ẹni naa jade.”
Ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Abilekọ Adeṣẹyẹ Margaret, naa fidi isẹlẹ yii mulẹ, nibi ti Ọgbẹni Amọdu Ṣakiru ti ṣoju rẹ.
Ọkunrin naa sọ pe, “Ni nnkan bii aago mẹta ku iṣẹju mẹtadinlogun (2:47 pm), ni awọn kan pe wa ni ipe pajawiri lati fi to wa leti pe ọkunrin kan ti ko sinu omi ọsa, lẹsẹkẹsẹ la si ti wa sibi lati ṣawari ẹni naa, ti igbesẹ naa ṣi n tẹsiwaju. A oo maa fi to yin leti bo ṣe n lọ.