Monisọla Saka
Pasitọ agba ati oludasilẹ ijọ Fountain Of Life Church, Pasitọ Taiwo Odukọya, ti faye silẹ.
Lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn ni baba naa dagbere faye lorilẹ-ede Amẹrika, lẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin (67).
Ninu ọrọ awọn ọmọ ijọ naa lasiko ti wọn n kede iku ojiṣẹ Ọlọrun naa, ni wọn ti ni, “Gbogbo ijọ Fountain Of Life Church, n kede ipapoda sinu ogo baba wa, olukọ, ati olusin Ọlọrun Ọga Ogo pẹlu ijupajusẹ si Ọlọrun, Pasitọ Daniel Taiwo Odukọya, ti wọn jẹ oludasilẹ ile ijọsin The Fountain of Life Church, ti wọn jade laye lọjọ keje, oṣu Kẹjọ ọdun yii, lorilẹ-ede Amẹrika”.
“A juwọ jusẹ silẹ fun Ọ, Ọlọrun. A dupẹ lọwọ rẹ fun ẹbun iru adari rere bayii!”
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 1956, ni wọn bi oloogbe niluu Kaduna, lapa Oke-Ọya.
O kawe alakọọbẹrẹ rẹ ni Baptist Primary School, Kigo Road, niluu Kaduna, ati ileewe girama St. Paul’s College, Zaria, nipinlẹ Kaduna.
Lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2005, niyawo oloogbe, Arabinrin Bimbọ Odukọya, faye silẹ lasiko ti ẹrompileeni Sosoliso Airlines ja, tawọn eeyan bii mẹtalelọgọrun-un si ba a lọ.
Bakan naa ni iyawo keji to fẹ lẹyin iku obinrin yii, Pasitọ Nomti naa faye silẹ lọjọ kesan-an, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.Ajalu awọn iyawo mejeeji yii wa ninu ohun ti wọn lo ṣeku pa ọkunrin naa.
Nigba aaye rẹ, Pasitọ Odukọya ni Pasitọ agba The Fountain Of Life Church, Ilupeju, nipinlẹ Eko.