Faith Adebọla
Iṣekuṣe to ti jaraaba awọn afurasi ọdaran meji yii, Umaru Hassan, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ati Alhassan Hussaini, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti sin wọn de akata awọn agbofinro bayii, afaimọ si ni iwa abeṣe ti wọn fẹsun rẹ kan wọn ọhun ko ni i sin wọn de gberegbere ọgba ẹwọn, latari bi wọn ṣe ni awọn mejeeji yii ki awọn ọmọdebinrin mẹta tọjọ ori wọn wa laarin ọmọọdun mẹjọ si mẹsan-an pere, wọn si fipa ba wọn laṣepọ ni ilu Auyo, nijọba ibilẹ Auyo, ipinlẹ Jigawa, ti wọn jọ n gbe.
Awọn ẹṣọ aabo ara-ẹni laabo ilu, iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), tawọn eeyan tun mọ si sifu difẹnsi ni wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi ọdaran mejeeji yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023.
Agbẹnusọ fawọn sifu difẹnsi sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ yii, pe baba ọkan lara awọn ọmọdebinrin ti wọn ba ṣaṣemaṣe naa lo mẹjọ wa si tọlọpaa, oun lo fọrọ naa to awọn leti.
Alukoro ni Umar yii lawọn ti kọkọ mu ni Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, to kọja.
Wọn ni baba to waa fẹjọ sun naa sọ pe inu ẹkun ni iyawo oun wa lasiko naa, awọn ko le sun mọju nigba tawọn gbọ bi afurasi ọdaran ti wọn pe ni Umar yii ṣe ṣe ọmọbinrin awọn baṣubaṣu.
Amọ ni teṣan, Umar ni ọrọ ko ri bẹẹ, o loun o fipa ba ọmọbinrin yii laṣepọ, o ni ni tododo, oun bọ pata idi ẹ, oun si fi ika ro o labẹ, amọ awọn ko ṣe ‘kinni’ gan-an, sibẹ ọmọdebinrin yii ni igba mẹta ọtọọtọ lafurasi naa ti huwa ifipabanilopó pẹlu oun, o ni ki i ṣe ika lo n lo, o lo maa n yọ nnkan ọmọkunrin ẹ soun ni gidi ni.
Ọmọdebinrin yii lo taṣiiri fawọn ọlọpaa pe ki i ṣoun nikan ni wọn daṣa palapala naa si, o ni wọn tun un ṣe fawọn ọrẹ oun kan tawọn jọ n lọ sileewe, eyi si lawọn ọlọpaa gbọ ti wọn fi tọpinpin ọrọ de ọdọ Hussaini, ẹni tawọn ọmọleewe meji mi-in fẹsun ifipabanilopọ kan, ti wọn fi mu oun pẹlu.
Wọn ni lọwọ kan loun ti jẹwọ ẹṣẹ to da naa, o ni ki wọn fori jin oun.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.