Lamido Sanusi ṣabẹwo sawọn ṣọja to ditẹ-gbajọba ni Niger

Faith Adebọla

Ọga agba banki apapọ ilẹ wa nigba kan, to si tun ti figba kan jẹ Ẹmia ilẹ Kano, Alaaji Sanusi Lamido Sanusi, ti ṣabẹwo sawọn ṣọja ti wọn gbajọba lorileede Niger, bẹẹ lo si ti lọọ jabọ abẹwo pataki rẹ ọhun fun Olori orileede wa, Bọla Ahmed Tinubu.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ yii ni Sanusi ṣabẹwo rẹ ọhun, to si jokoo ipade bonkẹlẹ kan pẹlu awọn olori ṣọja ti wọn n ṣejọba lọwọ nilẹ Niger ọhun. Ilu Niamey, ti i ṣe olu-ilu orileede Niger ni wọn ti gba a lalejo.

Bakan naa ni Sanusi ti fidi rẹ mulẹ pe ki i ṣe Olori ajọ Economic Community of West African States, ECOWAS, iyẹn Tinubu, lo ran oun lọ sọhun-un, o ni oun lo idanuṣe ara oun ni, gẹgẹ bii eekan kan ninu ẹgbẹ ẹlẹsin Musulumi Tijjaniya, eyi ti ọpọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa wa lorileede Niger. Sanusi lo wa nipo Khalifa ẹgbẹ Tijjaniya ọhun lọwọlọwọ.

Ninu fọto ati fidio kan to n ja ranyin lori ayelujara, wọn ṣafihan Ṣanusi, nibi to ti jokoo apero pẹlu awọn olori ṣọja Niger, ati bi wọn ṣe gba ọkunrin naa tọwọ-tẹsẹ lasiko abẹwo rẹ. Sultan ti ilu Damagaran wa lara awọn to kọwọọrin pẹlu Sanusi lọ sipade ọhun. Ipo kẹta ni ilu Damagaran yii wa laarin awọn ilu to tobi ju lọ nilẹ Niger.

Ninu ọrọ ṣoki kan to sọ fawọn oniroyin lori abẹwo rẹ ọhun, Sanusi ni: “Mo wa lati sọrọ ilaja ati ipẹtu-saawọ pẹlu olori ologun, Jẹnẹra Abdourahamane Tchiani, ni. Mo ti ba olori ijọba ologun naa sọrọ, ma a si lọọ fi abọ ajọsọ wa jiṣẹ fun Aarẹ Tinubu,” Amọ o fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe ijọba tabi ECOWAS lo ran oun wa silẹ Niger.

Bi Ṣanusi ṣe pari ijiroro rẹ pẹlu awọn ṣọja naa ti wọn si sin in sọna, taara lo balẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, nibi to ti lọọ jiroro pẹlu Aarẹ Bọla Tinubu, wọn si tilẹkun mọri sọrọ, laṣaalẹ ọjọ Wẹsidee naa.

Bakan naa ni Sanusi sọ fawọn oniroyin l’Abuja pe: “Asiko yii ki i ṣe eyi ta a maa da ọrọ yii da ijọba nikan, ọrọ ifikunlukun ati igbọra-ẹni-ye gidi lo ṣẹlẹ yii. Awọn eeyan Naijiria ati ti ilẹ Niger gbọdọ fọwọ sowọ pọ lati wa ojuutu to maa ṣanfaani fun ilẹ Afrika lapapọ, to si maa ṣe tolori tẹlẹmu loore.

Nigba ti wọn beere boya ijọba Naijiria lo ran an lọ, Sanusi ni, “rara, ijọba o ran mi niṣẹ, amọ mo fi ọrọ abẹwo mi to awọn alaṣẹ wa leti, wọn si mọ pe mo n lọ sọhun-un, ṣugbọn idanuṣe ara mi ni mo fi lọ, emi si ni mo kan si awọn ti mo mọ lọhun-un ti wọn fi ni ki n maa bọ. Gbogbo nnkan to ba wa nikaapa mi ni ma a ṣe lati yanju iṣoro naa, tori nnkan to yẹ ki n ṣe gẹgẹ bii adari kan ni.”

Ṣanusi lo sọrọ bẹẹ.

Leave a Reply