Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti sọ pe oun ko ni i dawọ ijo jijo tawọn eeyan mọ oun mọ duro rara, nitori ọna kan ṣoṣo ti oun mọ lati fi gbe Ọlọrun ga niyẹn. Ṣugbọn ọkunrin naa ni ijo jijo ọhun ko ni i di iṣejọba to duroore lọwọ, nitori idi ti awọn araalu fi dibo fun oun ni pe wọn nigbagbọ pe oun yoo ṣe daadaa.
Nibi ipade awọn lookọlookọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun to waye niluu Oṣogbo, ni gomina ti rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati dariji gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ ta ko aṣeyọri ẹgbẹ wọn lasiko idibo to kọja.
O ni ki wọn gbagbe gbogbo nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin, ki wọn fa awọn ti wọn n pada sinu ẹgbẹ mọra, ki wọn si ṣiṣẹ pẹlu oun lati gbe ipinlẹ Ọṣun goke agba.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Gẹgẹ bii gomina, mo gbagbọ ninu iṣakoso ẹgbẹ, mo si maa ri i pe ibawi wa ninu gbogbo nnkan ti a ba n ṣe, to fi mọ yiyan awọn igbimọ fidi-hẹ si awọn ijọba ibilẹ kaakiri.
‘A ni lati dariji ara wa. Awọn ti wọn yapa si wa tẹlẹ ti pada sinu ẹgbẹ, mo si fẹ ki gbogbo wa gba wọn tọwọ-tẹsẹ. Nipasẹ eleyii ni ẹgbẹ wa yoo fi maa le tente l’Ọṣun.
‘Awọn kan sọ pe mo fẹran ijo, mi o ni i da a duro rara, bi mo ṣe n jo naa ni ma a maa jo, ọna ti mo n gba yin Ọlọrun niyẹn. Mo ti fi han bayii pe mo mura silẹ fun iṣejọba. Gbogbo ipinlẹ lo n ṣawokọṣe nipa ipinlẹ Ọṣun bayii.
‘Mo fẹẹ rọ gbogbo awọn ti wọn ko ti i ri nnkan kan ninu ijọba yii pe ki wọn ṣe suuru, diẹdiẹ ni, o maa kan wọn, ki awọn to si ti kan naa pin iṣẹ rere yii kari’
Nibi ipade naa ni Alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi, ti kede orukọ Amofin Kamọrudeen Ajiṣafẹ, gẹgẹ bii ẹni ti yoo rọpo igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ PDP niha Iwọ-Oorun orileede yii, Ọnọrebu Sọji Adagunodo, to doloogbe.