Ọkọ akẹru kọ lu mọto mẹfa lori ere l’Ekoo, eeyan meji lo ku lẹsẹkẹsẹ

 Faith Adebọla

O kere tan, eeyan meji ti kagbako iku ojiji, nigba tawọn marun-un mi-in wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu, latari ijamba ọkọ to waye lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ yii.

ALAROYE gbọ pe ọkọ akẹru gagara MAC kan to ni nọmba T-1501 LA, ti ẹru kun ẹyin rẹ temutemu lo padanu ijanu rẹ bo ṣe n ba ere buruku bo lati ori biriiji Eko wa si agbegbe Alaka, ni Surulere, nijọba ibilẹ Surulere, ipinlẹ Eko.

Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, amọ ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe gbara ti bireeki ọkọ akẹru naa ti feeli, ni ọkọ nla naa ti n juwọ barabara, o jọ pe dẹrẹba naa n wa nnkan kan to le fi da ọkọ ọhun duro lori ere ni.

O nibi ti ọkọ ọhun ti n ya kiri lo ti bẹrẹ si i kọ lu awọn ọkọ ti wọn wa nitosi rẹ.

Ijamba yii lo ṣokunfa bi awọn ọkọ mi-in ṣe n fori sọ ara wọn, tawọn mi-in si n gbokiti. Ọkọ akero kekere ti wọn n pe ni ‘Korope’ meji si wa laarin wọn.

Nigba ti eruku akọlukọgba naa yoo fi rọlẹ, eeyan meji ti doloogbe, ọpọ lo si fara pa yanna-yanna.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alakooso eto iroyin ati ilanilọyẹ fun ajọ to n ri si lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko, Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), Ọgbẹni Taofeek Adebayọ, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori ijamba naa pe ọkunrin kan ati obinrin kan ni wọn doloogbe loju-ẹsẹ. O leeyan marun-un lawọn ri fa yọ, lara awọn to fara gbọgbẹ gidigidi, awọn si ti gbe wọn lọ sọsibitu.

Nọmba awọn ọkọ to fara gba ninu iṣẹlẹ naa ni ọkọ jiipu Lexus kan, LSP 795 EW; ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan, AKD 606 HH; ọkọ Toyota kan, LND 217 GX, bọọsi Korope kan, FKJ 77 YG.

Ọga agba ajọ LASTMA, Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba, fi anfaani yii rọ awọn onimọto lati maa rọra sare, ki wọn si ri i daju pe iṣiṣẹ ọkọ wọn peye, bireeki rẹ si duro san-un ki wọn too gbe ọkọ soju titi.

Leave a Reply