Obinrin yii daju o! Inu pata ọmọọdun mẹwaa lo fi n gbe egboogi oloro kiri l’Ekoo

Faith Adebọla

 Iyalẹnu lọrọ obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, ti wọn porukọ ẹ ni Taiwo, to n gbe lagbegbe Agege nipinlẹ Eko, okoowo egboogi oloro gbigbe lobinrin naa n ṣe, o si ti pẹ nidii ẹ, amọ ọgbọn buruku to n da tawọn agbofinro ko fi tete ri i mu latọjọ yii ni pe inu pata tọmọbinrin ọmọọdun mẹwaa kan, to jẹ ọmọ aburo rẹ, n wọ sidii lo maa n tọju ọja ofin naa si, ọpọ igba tawọn ọlọpaa ba si n yẹ ẹru ẹ wo, wọn ki i fura pe abẹ ọmọ lo ko kinni si, amọ ọwọ palaba rẹ ti segi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to ṣafihan obinrin naa pẹlu ọmọde ọhun lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko, to wa n’Ikẹja, lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ ta a wa yii sọ pe alaaanu ara Samaria kan to ri bi ọmọdebinrin ọhun ṣe n ri gberegbere kiri  adugbo kan l’Agege, lo da ọmọ naa duro lati bii leere ibi to n lọ ati ibi to ti n bọ, nigba ti ọrọ rẹ ko si lọ geere, ni wọn lọọ fa a lawọn ọlọpaa lọwọ.

Wọn lọmọ ọhun dọti bii ẹlẹdẹ ni, ni teṣan n ni wọn ba ni ki agbofinro kan wẹ fun un, ki ara ẹ le tubọ balẹ, ibẹ si lakata ti tu sepo, nigba tọmọ naa bọ pata ẹ, ti wọn ba lailọnu egboogi oloro ti wọn di pamọ si i labẹ.

Ọmọ naa ṣalaye fawọn ọlọpaa, o ti tun alaye kannaa ṣe fawọn oniroyin pe ẹgbọn iya oun, toun maa n pe ni ‘Mọmi,’ iyẹn afurasi ọdaran to n jẹ Taiwo yii, lo di ẹru ofin naa soun labẹ, o ni bo ṣe maa n fi egboogi oloro ran oun lọ bawọn kọsitọma ẹ niyẹn.

Ọmọ naa ni ohun ti Mọmi yii n ṣe ko tẹ oun lọrun, o si ya oun lẹnu nigba akọkọ to ṣe e, ṣugbọn alaye tiyaa naa ṣe foun ni pe tori kawọn ọlọpaa ma baa fura tabi mu awọn loun ṣe da ọgbọnkọgbọn bẹẹ.

Ọmọbinrin naa sọ pe ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara lawọn obi oun gan-an wa, o ni Mọmi yii, to jẹ ẹgbọn iya oun lo waa mu oun lati Ilọrin wa s’Ekoo pe koun maa waa gbe lọdọ oun, amọ latigba toun ti de ọdọ wọn, iṣẹ gbigbe egboogi oloro sinu pata lo n fi oun ṣe.

Aṣiri to tu yii lo mu kawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tubọ tọpinpin ti wọn fi de ile ti Taiwo n gbe, wọn si lọọ fi pampẹ ofin gbe e.

Hundeyin ni afurasi naa ko jampata pẹlu awọn ọlọpaa rara, o ni gbogbo ohun tọmọdebinrin naa sọ, ootọ ni, o loun ṣokoowo egboogi oloro, oun ko si ṣẹṣẹ maa ṣe e, ati pe ọpẹlọpẹ ọgbọn buruku toun da lati maa gbe e sinu pata ọmọbinrin naa ni ko jẹ kọwọ ti tẹ oun.

O tun sọ pe nnkan bii oṣu mẹta sẹyin ni ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Azeez fi ọna okoowo buruku naa han oun, loun fi kara bọ ọ.

Ṣa, wọn ti taari afurasi yii si ẹka ileeṣẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin. Alukoro ni awọn maa wa awọn obi ọmọ naa kan, ki wọn le fa ọmọdebinrin ọhun le wọn lọwọ, bẹẹ lo tubọ ṣekilọ fawọn obi pe ko daa ki wọn kan maa yọnda ọmọ wọn fun ẹnikẹni laimọ ohun to n ṣẹlẹ sọmọ ọhun, o ni ojuṣe obi ni lati tọ awọn ọmọ wọn funra wọn.

Leave a Reply