Abdulateef ti wọn mu ni: Mi o mọ pe iwa ọdaran ni ki eeyan maa ji ina ijọba lo 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Abdulfatai Abdulateef, ti sọ pe to ba jẹ pe oun mọ pe iwa ọdaran to nijiya labẹ ofin ni jiji ina lo ni, oun ko ni i ṣan iru aṣọ bẹẹ ṣoro.

Lateef ati ẹni keji rẹ, Adeṣina Ọpẹyẹmi, to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn, ni ọwọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ọṣun tẹ laipẹ yii lori ẹsun pe wọn n ji ina ijọba lo.

Nigba to n ṣafihan wọn fun awọn oniroyin niluu Oṣogbo l’Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, kọmandanti ajọ naa, Sunday Agboọla, ṣalaye pe agbegbe Akéde, ni Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo, lọwọ ti tẹ awọn mejeeji.

Agboọla ṣalaye pe lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lawọn mejeeji yii gbimọ-pọ lati yọ waya kuro nidii mita ile ti wọn n gbe, ti wọn si bẹrẹ si i ji ina ìjọba lo.

O ni eleyii ni wọn n ṣe lọwọ ti ọwọ awọn sifu difẹnsi pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa IBEDC fi tẹ wọn.

Ninu awijare rẹ, Lateef ṣalaye fun akọroyin wa pe bi owo ina ti awọn ba ra ṣe tete maa n tan lo fa a ti oun ati ẹni kẹji oun fi pinnu lati yara ji ina lo lọjọ naa.

O ni ẹrọ omi (water pumping machine) lawọn fẹẹ lo lọjọ ti ọwọ tẹ awọn, ati pe igba akọkọ ti oun yoo ṣe iru nnkan bayii ri niyẹn, oun ko si mọ pe iwa ọdaran to le gbe oun de ọdọ awọn ẹṣọ alaabo ni.

Amọ ṣa, Agboọla ti sọ pe awọn ọkunrin mejeeji yoo foju bale-ẹjọ nitori iwa to n ṣakoba fun eto ọrọ-aje orileede yii ni wọn hu.

Bakan naa lo ṣafihan Akinloye Abiọla, ẹni ọdun mejilelọgbọn, lori ẹsun dida omi alaafia agbegbe ru.

Abiọla ni wọn ni o lọ maa n fi igba gbogbo dunkooko mọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ iwakusa kan niluu Ileṣa.

Agboọla ṣalaye pe ni kete tiwadii ba ti pari ni Abiọla yoo foju bale-ẹjọ lati sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Leave a Reply