Mo nilo ẹran ara oku lati fi joogun ni mo ṣe lọ si itẹkuu – Mubarak

Adewale Adeoye

Iwaju adajọ ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Ọgba, Onidaajọ Abilekọ Fajana Oyenikẹ ni wọn wọ Ọgbẹni Mubarak Kajọla Noah, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan lọ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe lọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, lo lọ si itẹku kan to wa niluu Ipaja-Ayọbọ, niluu Eko, to lọọ ji ara ẹran oku ti wọn sin sibẹ, ṣugbọn ọwọ awọn ọdẹ to n ṣọ itẹkuu naa to o, ti wọn si fa a le ọlọpaa teṣan Ayọbọ lọwọ, ki wọn le ba a ṣẹjọ fohun to ṣe.

Ni teṣan ọlọpaa to wa ni Mubarak ti jẹwọ fawọn agbofinro pe oun nilo diẹ lara ẹran oku ọhun gidigidi ni lati fi jo oogun loun ṣe lọ si itẹkuu ohun, ko too di pe ọwọ to oun.

Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Matthew Ikhaluode, to foju Mubarak bale-ẹjọ fẹsun mẹta kan an. Akọkọ ni pe o lọọ si itẹkuu lọganjọ oru lati lọọ ji ara ẹran oku, ekeji ni pe olujẹjọ ọhun tun ba irin ti wọn fi daabo bo ọgba itẹkuu naa, eyi ti awọn lanlọọdu adugbo ‘Ayobo-Ipaja LCDA’ ṣe lowo to le ni milliọnu kan Naira. Ẹsun kẹta, ni pe o hu iwa ọdaju sawọn oku ti wọn wa ninu saare jẹẹjẹ wọn.

Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ pata ni agbefọba ni ofin ipinlẹ Eko ko faaye gba rara.

Lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun ọhun si i leti tan ni Mubarak jẹwọ fun adajọ  pe loootọ loun jẹbi.

Siwaju si i, olujẹjọ ohun ni idi toun ṣe lọ sibẹ ni pe oun nilo diẹ lara ẹran oku lati fi ṣoogun ni.

Gbara ti olujẹjọ  ti gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni olupẹjọ ni ki adajọ ile-ẹjọ ṣe idajọ rẹ ni kia, ko le jẹ ẹkọ nla fawọn kọọkan ti wọn ni i lọkan lati hu iru iwa palapala ti Mubarak hu yii lawujọ.

Adajọ ni ki wọn lọọ ju u sọgba ẹwọn Kirikiri to wa niluu Eko, titi digba ti igbẹjọ maa fi waye lori ọrọ rẹ.

O sun igbẹjọ siwaju di ọjọ miran

 

Leave a Reply