Tinubu, kuku jẹwọ fawọn ọmọ Naijiria pe o ko ni iwe-ẹri alakọbẹrẹ ati girama -Atiku

Jamiu Abayọmi

Oludije sipo aarẹ orilẹ-ede yii ninu ẹtọ idibo to kọja labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) Alhaji Atiku Abubakar, ti tun gbọna ara yọ si Aarẹ Bọla Tinubu lori ọrọ satifikeeti tẹjọ rẹ n lọ lọwọ nile-ẹjọ pe ko ko awọn iwe-ẹri to gba jade nileewe alakọọbẹre ati ti girama  to loun lọ jade sita kawọn ọmọ Naijiria ri i.

Atiku fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, to si fika tọ ọ nibẹ pe, Tinubu  loun lọ sileewe alakọọbẹrẹ ‘St.John, ni Arọlọya, niluu Eko, bakan naa, lo tun loun lọ si Children’s Home School, niluu Ibadan.

Lẹyin naa lo tun loun lọ sileewe Government College, niluu Ibadan yii kan naa, o tun loun lọ si Richard Daley College, koun too tun lọ si Yunifasiti ilu Chicago, lorilẹ-ede Amẹrika. Gbogbo iwe-ẹri wọnyi lo yẹ ko fi sita kawọn ọmọ Naijiria foju ri.

Igbakeji aarẹ nigba kan ọhun  waa rọ Tinubu pe ko kuku jade, ko si sọ gbangba pe oun ko lọ sileewe alakọọbẹrẹ ati ti girama, dipo bo ṣe n yi awọn ọmọ Naijiria si poro, to tun n yi wọn soju ebe nigba gbogbo yii.

“O jẹ nnkan ti ko ye ẹnikẹni, bawo leeyan ṣe maa ni iwe-ẹri ileewe giga fasiti ti ko si ni i le ko ti ileewe alakọọbẹrẹ ati ti sẹkọndiri rẹ jade.

“Eleyii yatọ gedegede si ẹjọ to n lọ lọwọ lori ọrọ iwe-ẹri ti Fasiti ilu Chicago o, eyi ni pe ko jade bọ sita waa ṣalaye  ara rẹ lori awọn iwe-ẹri ileewe alakọọbẹrẹ rẹ.

“O yẹ ki awọn ọmọ Naijiria bi i leere bo ṣe rin irinajo rẹ naa, tabi ko kuku bọ sita waa sọ pe oun ko lọ sile-iwe wọnyi rara.”

Bayii ni ọkunrin naa tun pe Tinubu nija lori ọrọ iwe-ẹri to n ja ranyin lọwọ bayii nile-ẹjọ.

Leave a Reply