Awọn Oniṣẹṣe rawọ ẹbẹ sijọba Ondo, wọn lawọn n fẹ ayajọ ọdun iṣẹṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ awọn Oniṣẹṣe nipinlẹ Ondo ti rawọ ẹbẹ sijọba Rotimi Akeredolu lati ya ọjọ kan sọtọ bii ọjọ Iṣẹṣe gẹgẹ bii ohun tawọn ipinlẹ kan ti ṣe saaju.

Awọn ẹgbẹ ọhun fi aidunnu wọn han si bi ijọba ipinlẹ Ondo ṣe kuna lati darapọ mọ awọn ipinlẹ bii Ogun, Eko, Ọṣun ati Ọyọ ti wọn kede ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lati fi ṣami si ọjọ naa.

Olori ẹgbẹ awọn Oniṣẹṣe, ẹka ti ipinlẹ Ondo, Oloye Temiadara Ariwajoye, to gba ẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ sọrọ lasiko ayẹyẹ ayajọ ọdun Iṣẹṣe ti ọdun yii, eyi ti wọn ṣe ninu gbọngan aṣa Adegbenle, niluu Akurẹ, ni gbogbo ilu, agbegbe ati ipinlẹ ti wọn ba ti n sọ ede Yoruba lo yẹ kí wọn ti maa ya ogunjọ, oṣu Kẹjọ, sọtọ fun ọdun Iṣẹṣe.

Ọkunrin ti wọn n pe ni Ọba aṣa agbaye ọhun ni ohun ti ayajọ yii wa fun ni lati ṣafihan pataki ọdun Iṣẹṣe ati fun igbelarugẹ aṣa Yoruba.

O ni ohun ti ko tọna rara ni oju idọti ati ẹgbin tawọn ẹda kan fi n wo ọdun Iṣẹṣe, eyi lo ni ko yẹ ko ri bẹẹ nitori ko sohun meji ti awọn baba nla iran Yoruba fi le wọn lọwọ ju iṣẹṣe lọ.

Leave a Reply