Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, ti kede Sálà Ayọdeji, to lọọ dunkooko mọ Tajudeen ati iyawo rẹ ni ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹlifiṣan lagboole Aláràn-án, niluu Ilọrin, gẹgẹ bii afẹmiṣofo, iyẹn tẹrọriisi, tawọn si n wa a bayii. O ni ọwọ ofin yoo tẹ ọmọkunrin naa laipẹ, tori pe ẹgbẹrun saamu rẹ ko le sa mọ ofin lọwọ.
Ọga ọlọpaa kede ọrọ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, lasiko to ni ki awọn mọlẹbi Ayọdeji, mọlẹbi Aláràn-án, ati Tajudeen waa rojọ lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye. Ninu ọrọ Adelesi, o ni dandan ni kawọn mọlẹbi lọọ wa Ayọdeji wa nibikibi ti wọn ba mọ, nitori pe iwa ọdaran, tẹrọriisi, lo hu labẹ ofin, ọwọ ofin si gbọdọ tẹ ẹ. Yatọ si iwa buruku to hu, o tun ba ọlọpaa lorukọ jẹ.
Kọmiṣanna beere lọwo awọn mọlẹbi Ayọdeji pe ki lo de ti wọn ko le pe ọmọ wọn si akiyesi, ṣe wọn fẹẹ da Naijiria ru ni, ṣe tori pe iyawo Tajudeen jẹ ọmọ ipinlẹ Ọsun, ṣe iyẹn tumọ si pe o n ṣe ẹsin Iṣẹse, abi ko si Musulumi nipinlẹ Ọsun.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu iwa tawọn ara ile Aláràn-án hu pẹlu bi wọn ṣe gbimọ-pọ le Tajudeen ati iyawo rẹ lojiji pe ki wọn kẹru jade, ti wọn si ko owo ti wọn fi gba ṣọọbu naa le wọn lọwọ.
O ni dandan ni kawọn baba Ayọdeji wa ọmọ wọn lawaari ni gbogbo ibikibi to ba sa lọ, ki wọn si waa fa a le ọlọpaa lọwọ o pẹ ju, Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, bẹẹ lo ni awọn agbofinro paapaa yoo maa wa a.
Ninu esi ti awọn mọlẹbi fun kọmiṣanna ni wọn ti sọ pe lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni awọn ti n wa ọmọ awọn, ti ko si wale, bẹẹ ni nọmba ibaniṣọrọ rẹ ko lọ.
Tajudeen ni oun fi ọrọ Ayọdeji le Ọlọrun lọwọ, oun ko ni ẹjọ kankan lati ba a jẹ, nitori pe awọn mọlẹbi Ayọdeji ti waa bẹbẹ, ṣugbọn esi ti kọmiṣanna fun un ni pe ọlọpaa ti ṣetan lati ba Ayọdeji sẹjọ tori pe o tun ba awọn agbofinro lorukọ jẹ.