Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejọ yii, ni ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, gba beeli Oniṣẹṣe kan, Abẹbi Ẹfunṣetan Yakubu, ti ọpọ eeyan mọ si Oloriṣa ati Ọbalowu Jimọh, lẹyin ti wọn lo ọjọ mọkandinlọgbọn lọgba ẹwọn lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan wọn.
Tẹ o ba gbagbe Ọmọọba Ademọla Ajaṣa lo wọ awọn Oniṣẹṣe mejeeji yii lọ sile-ẹjọ lorukọ Aafaa Okutagidi, to n gbe ni No 105, lagbegbe Pàkátà, niluu Ilọrin. Nibi ti wọn ti fẹsun kan awọn olujẹjọ mejeeji pe wọn ya fidio kan to gba gbogbo ori ayelujara, nibi ti Iya Ọṣun Abẹbi ti ni oun ran Aafaa Okutagidi lọwọ ti iyawo rẹ fi rọmọ bi, ati pe oun gbẹbi fun iyawo rẹ.
Eyi lo mu ki wọn fẹsun igbimọ-pọ, ibanilorukọ jẹ, ati dida omi alaafia ilu ru kan Abẹbi ati Ọbalowu, ti adajọ si fibinu sọ wọn sẹwọn.
L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Onidaajọ Muhammad Adam, gba beeli awọn mejeeji pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000) pẹlu oniduuro meji, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.