Jamiu Abayọmi
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta kede pe ọwọ awọn ti ba awọn afurasi ọdọmọkunrin ti wọn ko din ni ọgọrun-un niye, nibi ti wọn ti n ṣe igbeyawo akọ-si-akọ nileetura kan nipinlẹ naa.
Nigba ti wọn n ṣafihan awọn ọmọkunrin ọhun, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Bright Edafe, sọ pe lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, lọwọ tẹ awọn eeyan naa lasiko ti awọn agbofinro n yide kiri ilu ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ.
O ni nibi ti awọn ọkunrin yii ti fẹẹ maa gbe ara wọn niyawo, eyi ti wọn pe ni ‘Igbeyawo alaṣọ funfun’ lawọn lọọ ka wọn mọ lotẹẹli kan to wa ni oju ọna Rifinery, nijọba ibilẹ Uvwie, tawọn si ko gbogbo wọn.
O fi kun un pe awọn yoo ba awọn ọmọkunrin naa ṣẹjọ ni ilana ofin Naijiria to lodi si ki akọ ati akọ maa fẹra wọn.
Lasiko tawọn oniroyin n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo ni ọkan ninu wọn to mura bii obinrin ṣalaye pe eto kan ni oun wa fun, eyi ti wọn ti n ṣafihan aṣọ, to si pe fun imura ti oun mu yii. Ṣugbọn nigba ti wọn bi i pe ibi ti eto yii ti fẹẹ waye lo yẹ ko ti mura, ati pe ṣe o mọ pe awọn ọkunrin ati ọkunrin lo fẹẹ ṣegbeyawo ni otẹẹli ti wọn ka a mọ ọhun, o ni oun ko mọ. Ṣugbọn imura ọmọkunrin naa ati isọrọ rẹ jọ ti obinrin. Niṣe lo wọ aṣọ obinrin, to de wiigi sori, to si tọ ete, bẹẹ lo rọra gbe baagi kekere tawọn sisi maa n gbe lọwọ, to si tun wọ bata gogoro.
Oun nikan kọ lo mura bayii. Ọpọ ninu awọn ọkunrin ti wọn mu yii ni wọn mura bii obinrin, awọn kan wa ninu wọn ti wọn asọ igbeyawo funfun, awọn mi-in wọ aṣọ awọ mi-in to jẹ ti obinrin, ti wọn si pọ daadaa niye.
Bẹ o ba gbagbe pe ọdun 2014 ni aarẹ orileede yii nigba kan ri Goodluck Ebele Jonathan, ti buwọlu ofin to ta ko ibalopọ akọ-si-ako tabi abo-si-abo, ẹnikẹni tọwọ ba si ba yoo ṣe to ẹwọn ọdun mẹrinla gbako fun ẹṣẹ naa.