Jamiu Abayọmi
Titi di asiko ti a n ṣakojọ iroyin yii, inu ọfọ ati ipayinkeke ni awọn mọlẹbi ọmọkunrin pulọmba kan, Jimoh Kuton, wa. Eyi ko sẹyin bi ọkunrin naa ṣe mumi yọ ninu kanga lasiko to n ba wọn yọ ẹrọ ifami (Pumbing Machine) awọn aladuugbo rẹ kan to ja somi. Bo ṣe wọnu kanga-dẹrọ naa ni ko le jade mọ, to si mumi ku sibẹ lagbegbe Ijọtun, Badagry, niluu Eko.
ALAROYE gbọ pe ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to jẹ ọlọpaa, Ọfiisa Isa, lo bẹ ẹ niṣẹ l’ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lati ba a yọ ẹrọ ifami ọhun, eyi lo si fẹẹ ṣe to fi ko sodo, to si mumi ku sinu kanga naa. Gbogbo igbiyanju tawọn eeyan gba lati ri i fa yọ soke lo ja si pabo.
Ọmọ oloogbe naa, Tọpẹ, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin pe ọlọpaa naa lo kegbajare sita pe ki wọn gba oun pe baba oun ti ku sinu kangan.
“Ni nnkan bii aago meje aarọ lo ṣẹlẹ, ọlọpaa ni ọkunrin naa, alaamuleti wa ni, o sọ pe maṣinni ifami oun ja bọ sinu kanga, oun si ti pe to eeyan mẹta ọtọọtọ lati ba oun yọ ọ, ṣugbọn wọn kọ fun un, ko too waa pe baba mi, baba mi sigba lati ba a yọ ọ, koda wọn ti yọ ọ tan, ṣugbọn wọn o waa le jade sita mọ nitori omi naa ti pọ ju.
“A kan ri Isa to sunkun wale wa ni pe baba mi ti ku sinu omi, nigba ti awa ati awọn araadugbo yoo fi de idi kanga naa, awa naa ri i pe omi naa ti pọ ju, wọn o si le jade mọ.
“Ọkunrin naa lo si funra rẹ lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Ilogbo, lati lọọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, awọn ọlọpaa naa si wa pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ lati waa yọ oku oloogbe naa.
Alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, sọ pe ohun to jẹ awọn logun ni lati wadii boya ijamba lasan ni tabi ipaniyan.
“Lẹyin iwadii ti a n ṣe lori oku oloogbe naa, to ba jẹ ipaniyan ni, gbogbo awọn to ba lọwọ ninu rẹ lo maa fimu kata ofin, to ba si jẹ ijamba ni, tawọn mọlẹbi si fẹ nnkan lati ọwọ ẹni to gbeṣẹ fun oloogbe naa, ki wọn lọ sile-ẹjọ lati lọọ beere fun ẹtọ wọn”.