Adewale Adeoye
Adajọ ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Eko, Onidaajọ Akintayo Aluko, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fun awọn mẹsan-an wọnyi: Ọga ọlọpaa patapata orileede yii, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, gomina ipinlẹ Kwara, ẹgbẹ ‘Council Of Ulama’, Adajọ Saliu Mohammed ti i ṣe akọwe agba ẹgbẹ ‘Council Of Ulama, Sheikh Dokita Mohammed Basir Saliu, Imaamu Agba tiluu Ilorin, Alaga ẹgbẹ ‘Council Of Ulama, Afaa Abdulsalam Baba Tonile Okuta-Agidi, ile-ẹjọ Majisireeti tilu Ilọrin atawọn alaṣẹ ajọ to n mojuto awọn ẹlẹwọn ‘Nigeria Correctional Services’ ẹka tilu Ilọrin, niwee lati yọju si kootu.
Eyi ko sẹyin ẹjọ kan ti agbejọro kan, Olukọya Ogungbejẹ pe ta ko awọn eeyan naa pe wọn tẹ ẹtọ awọn onibaara awọn kan loju. Ninu iwe ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan loju ọhun ti nọmba rẹ je FHC/L/CS/1674/2023, eyi to gbe wa siwaju kootu naa lo ti beere fun awọn nnkan mẹjọ, eyi to fẹ ki ile-ẹjọ naa ṣe foun.
Lara rẹ ni pe ki ile-ẹjọ naa fofin de awọn olujẹjọ mẹsẹẹsan lapapọ, yala funra wọn tabi ti wọn ran aṣoju wọn, lati fọwọ ofin, ọwọ lile, halẹ tabi da eto awọn ẹlẹsin Iṣẹṣe ru mọ gẹgẹ bo ti ṣe wa ninu iwe ofin ilẹ wa ti ọdun 1999 pe ẹnikeni lẹtọọ labẹ ofin orile-ede wa lati ṣe ẹsin yoowu to ba fẹ
Ẹbẹ keji ni pe, ki ile-ẹjọ paṣẹ fun olujẹjọ akọkọ ati ikeji (ọga olọpaa patapata ati kọmiṣanna ọlọpaa Kwara) lati pese eto aabo to peye fawọn ẹlẹsin Iṣẹṣe gbogbo ti wọn wa ninu ilu naa, paapaa ju lọ, lakooko ti wọn ba fẹẹ ṣọdun ẹsin ti wọn ni igbagbọ ninu rẹ tabi ayẹyẹ kayẹyẹ mi-in ti wọn ba fẹẹ ṣe lai ṣe pe ẹnikẹni di wọn lọwọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin orile-ede wa tọdun 1999.
Ẹbẹ kẹta ni pe ki olujẹjọ kẹsan-an, iyẹn awọn alaṣẹ ajọ to n ri sọrọ awọn ẹlẹwọn ‘Nigeria Correctional Center’ ẹka ti ipinlẹ Kwara fi Ọgbẹni Adegbọla Abdulazeez, ẹni tawọn eeyan mọ si Ta-ni-Ọlọrun, Iyaafin Ẹfunṣetan Abẹbi Aniwura Oloriṣa ẹni tawọn eeyan mọ si Iya Ọṣun silẹ lahaamo wọn ni kia
Ẹbẹ kẹrin ni pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn fiwee ipẹjọ ṣọwọ si ọfiisi olujẹjọ kẹrin ti i ṣe imaamu agba tilu Ilọrin to wa ni Ọja Ọba, niluu Omu-Aran, niluu Ilọrin, nipasẹ awọn olujẹjọ karun-un, kẹfa ati ikeje.
Ẹbẹ karun-un ni pe kile-ẹjọ paṣẹ pe fifun awọn olujẹjọ karun-un, kẹfa ati ikeje niwee lori ọrọ yii jẹ ohun to daa, to si tọna.
Ẹbẹ kẹfa ni pe kile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn fiwee ipẹjọ ṣọwọ si olujẹjọ kẹjọ nipasẹ olujẹjọ kẹta ni ọfiisi adajọ agba ipinlẹ naa to wa lagbegbe Ahmadu Bello, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Ẹbẹ keje ni pe kile-ẹjọ paṣẹ pe fifi iwe ipẹjọ ranṣẹ si olujẹjọ kẹjọ lbojumu, o tọna, o ṣi dara labẹ ofin lori ẹjọ naa.
Ẹbẹ kẹjọ ni pe kile-ẹjọ paṣẹ pe ki olujẹjọ kẹjọ lọọ so ewe agbejẹ mọwọ na lori ọrọ Ọgbẹni Adegbọla Abdulazeez, ẹni tawọn eeyan mọ si Ta-ni-Ọlọrun, Iyaafin Ẹfunṣetan Abẹbi Aniwura Oloriṣa, ẹni tawọn eeyan mọ si Iya Ọṣun, titi igbẹjọ maa too fi waye lori ọrọ ọhun.
Lẹyin gbogbo atotonu lọọya olupẹjọ nile-ẹjọ naa, Onidaajọ Aluko sọ pe oun gbọ ẹbẹ kẹrin, ikarun-un, ikẹfa ati ikeje lori ẹjọ naa. Bakan naa lo ni ki ọn ma ṣe gba ẹbẹ akokọ, ikeji, ikẹta ati ikẹjọ.
Bakan naa ni adajọ ọhun paṣẹ pe ki wọn fawọn olujẹjọ mẹsẹẹsan niwee ipẹjọ lati fara han nile-ẹjọ ọhun. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.