Eyi ni Asẹyin tilu Iṣeyin tuntun tawọn afọbajẹ yan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn afọbajẹ ilu Iṣẹyin, nipinlẹ Ọyọ, ti yan Ọmọọba Ọlawale Sẹmiu Oyebọla gẹgẹ bii Aṣẹyin tilu Isẹyin tuntun.

Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lawọn afọbajẹ naa de si aafin pẹlu awọn eleto aabo to duro wamuwamu, lẹsẹkẹsẹ si ni wọn bẹrẹ si i dibo, eyi ti awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Iṣẹyin mojuto.

Abajade ibo ọhun lo fihan pe ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelaaadọta yii ni oṣuwọn rẹ kun ju lọ ninu gbogbo awọn ti wọn n dupo ọba ilu naa.

Ọmọọba Oyebọla ni Aṣẹyin ọgbọn (30) ti yoo jẹ lẹyin ti Ọba Abdganiy Salawudeen Adekunle Oloogunebi (Ajinẹsẹ Kin-in-ni) waja.

ALAROYE gbọ pe ilu Amẹrika lo ti n ṣiṣẹ, ibẹ lo si n gbe pẹlu awọn ẹbi ẹ, ṣugbọn ko figba kankan fọwọ yẹpẹrẹ mu ilọsiwaju ilu Isẹyin.

Lara iṣẹ idagbasoke to ti ṣe siluu Isẹyin ni idasilẹ ajọ kan to n ṣeranwọ ẹkọ-ọfẹ fawọn akẹkọọ ti ko ba lowo lati lọ sileewe giga.

Leave a Reply