Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara fẹyinti lẹnu iṣẹ

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Yoruba ni ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ki i lopin, igba ni yoo si rẹyin alogba,.eyi lo difa fun Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, to ti n dagbere lati fi ọfiiṣi silẹ lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn lẹnu iṣẹ ọlọpaa.
Ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, odun 1990 ni wọn gba Adelesi ṣiṣẹ gẹgẹ bii Cadet Assistant Superintended of Police, o sí ti ṣiṣẹ lawọn oniruuru teṣan lorile-ede Naijiria,  to si ti di oniruuru ipo mu.
Lara awọn ipinlẹ to ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọlọpaa ni Sabongeri, nipinlẹ Katsina, Mọkọla, Ẹlẹyẹle, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ. Llaarin ọdun 1991 si ọdun 2009, ni Adelesi jẹ ọga nileewe ti wọn ti n kikọ nipa iṣẹ ọlọpaa ni Ẹlẹyẹle, ati Agodi, nipinlẹ Ọyọ yii kan naa. Bakan naa ni o tun jẹ ọga nileewe gírama awọn obinrin ni Shanono, nipinlẹ Kano, ileewe Ṣẹkọndiri ọlọpaa ni Ukana, nipinlẹ Akwa-Ibom, ati ilu Port-Harcout, nipinlẹ Rivers.
O di ipo igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa mu nipinlẹ Imo, ipinlẹ Ogun, ipinlẹ Ọṣun, ipinlẹ Eko ati ipinlẹ Kwara, ko too tun pada si ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa, to si jẹ pe oun ni obinrin akọkọ ti yoo di kọmiṣanna ọlọpaa ninu iwe itan ipinlẹ naa.
Lẹnu oṣu meji ti CP, Adelesi gba ipo lọwọ Paul Odama, gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, o ti pitu meje tọdẹ maa n pa ninu igbo nipa gbigbogun ti iwa ọdaran, lasiko rẹ ni wọn mu awọn afurasi ajinigbe to n yọ awọn eniyan Ìsin, ni Guusu Kwara lẹnu, awọn to n ji kebu waya ijọba tu, awọn to n fipa ba ọmọde lo pọ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bakan lo lo ọgbọn ati oye rẹ lati ri i pe wahala ko sẹlẹ laarin awọn ẹlẹsin iṣẹṣe ati atawọn aafaa Ilọrin.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, ni CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, n ṣe ayẹyẹ ifẹyinti rẹ ati ṣiṣe ifilọlẹ iwe kan to kọ to pe ni “FUNCTIONAL POLICE MEMO” eyi to waye ni Gbọ́ngàn Banquet, to wa lagbegbe GRA, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu fun ipinlẹ Kwara, nibi ti awọn lookọ-looki ti lọọ ba a dawọọ idunnu, ti wọn si n ki i ku orire.
 Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ ọhun ni Abẹnugan ileegbimọ asofin ipinlẹ Kwara, Họnarebu Yakubu Danladi, Ọlọfa tilu Ọffa, Ọba Musbau Gbadamosi, Ẹmir tiluu Shonga, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply