Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Obinrin kan tawọn eeyan n pe ni Iya Baṣira, lawọn aja oyinbo meji ti sọ sinu ibanujẹ ayeraye bayii latari bi wọn ṣe yọ ọmọ to gbe pọn, ti wọn si fa a ya pẹrẹpẹrẹ.
Inu fẹnsi ile kan lagbegbe Halleluyah Estate, ni Ido-Ọṣun, nipinlẹ Ọṣun, la gbọ pe awọn aja oyinbo mejeeji naa ti fo jade laago mẹta ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Kongẹ igba ti obinrin yii, ẹni to gbe ọmọ rẹ, ọmọ oṣu marun-un pọn, de ẹgbẹ fẹnsi ọhun lawọn aja naa fo jade, wọn si bẹ mọ ọn lẹyin, wọn fi eyin yọ ọmọ ẹyin rẹ ko too sọ pe oun fẹẹ sa lọ.
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni bi wọn ṣe n ṣe ọmọ naa yannayanna ni iya rẹ n pariwo, ṣugbọn ko si araadugbo to le sun mọ awọn aja naa.
Lẹyin ti wọn pa ọmọ yii silẹ tan ni wọn tun pakuuru mọ iya rẹ nibi to ti n sunkun, ṣugbọn awọn ọkunrin ti sun mọ itosi nigba naa, wọn si fi igi le awọn aja naa lọ.
Bayii ni wọn gbe obinrin naa lọ sileewosan fun itọju, nitori awọn aja naa ṣe e leṣe diẹ gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Awọn araadugbo naa ṣalaye pe ko si ẹnikankan to n gbe inu ile ti awọn aja naa ti bẹ jade, ẹkọọkan ni awọn kan ti wọn nigbagbọ pe o ni ile naa maa n wa sibẹ.
A gbọ pe gbogbo aago awọn eeyan ti wọn maa n wa sile naa lawọn araadugbo pe, ṣugbọn ko si eyi to lọ nibẹ.
Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari awọn ti wọn ni awọn aja naa.
Ọpalọla ṣeleri pe ko si ẹlẹsẹ kan ti yoo lọ lai jiya nitori idajọ ododo yoo fẹsẹ mulẹ lori iṣẹlẹ laabi ọhun.