Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun nigba kan, Alhaji Rasaq Ṣalinṣile, ti sọ pe ope ati alailoye ni awọn ti wọn kede pe awọn yọ oun kuro ninu ẹgbẹ.
Ṣalinṣile ṣalaye pe ko tọ si eyikeyii ninu awọn ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju ẹgbẹ naa l’Ọṣun bayii lẹnu lati sọ pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ mọ.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni alaga ẹgbẹ naa, Sooko Tajudeen Lawal, kede yiyọ awọn eeyan mẹrinlelọgọrin kuro ninu ẹgbẹ. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n huwa to n ko itiju ba ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun.
Lara awọn ti wọn le ninu ẹgbẹ ni Alhaji Ṣalinṣile to jẹ alaga igun TOP ti awọn ọmọ Arẹgbẹṣọla da silẹ nigba naa, Alhaja Temilade Olokungboye to jẹ oludamọran pataki fun Gomina Adeleke lori ọrọ awọn ọmọde ati Dokita Biyi Ọdunlade to jẹ kọmiṣanna fun ọrọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ.
Lawal ṣalaye pe lẹyin ti awọn araalu fi oniruuru ẹsun ranṣẹ si ile ẹgbẹ lori awọn eeyan naa ni awọn alakooso ẹgbẹ gbe igbimọ oluwadii dide, awọn igbimọ naa ni wọn sọ pe awọn eeyan ọhun jẹbi.
Ṣugbọn ọkan lara wọn, Ṣalinṣile, ṣalaye pe igbesẹ ti ko le duro rara ni ikede naa, o ni alaimọkan ati alailoye ninu ọrọ ẹgbẹ oṣelu ni awọn ti wọn n dari ẹgbẹ APC lọwọlọwọ l’Ọṣun.
O ni ilana wa ninu iwe ofin ẹgbẹ APC lati da ẹnikẹni duro, ṣugbọn wọn ko tẹle ilana naa. O fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ ti pẹ ti ara ti ni awọn onigberaga ati awọn oloṣelu ẹtanu ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si ti n wa ọna lati le awọn.
Salinṣile sọ siwaju pe pupọ ninu awọn ti wọn sọ ara wọn di alaṣẹ ninu ẹgbẹ naa lonii ni wọn ko mọ bi awọn ṣe ko ẹgbẹ jọ lẹyin ijakulẹ ti wọn ni lẹyin ti wọn lulẹ lọdun 2023.
O ni, “Mo mọ pe oniwatutu ni Sooko Lawal, ṣe ni awọn kan kọ akọsilẹ idaduro naa fun un, ti wọn si ni ko buwọ lu u. Ohun ti mo mọ ni pe ofo ọjọ keji ọja ni igbesẹ ti wọn gbe yii”