Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni ilu ti ko sofin, ẹṣẹ ko si nibẹ rara, eyi lo mu kijọba ipinlẹ Eko laago ikilọ lori ohun ti wọn ko nifẹẹ si lati ọdọ awọn araalu ti wọn yoo maa wọ ọkọ reluwee ti awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ṣẹṣẹ fẹẹ ṣe ifilọlẹ rẹ lọjo kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, eyi ti wọn pe ni ‘Blue line rail’.
Lara ohun ti wọn lawọn ko nifẹẹ si lati ọdọ awọn araalu ti wọn yoo maa wọ ọkọ oju irin naa ni ki wọn maa jẹun tabi mu ohun mimu ninu ọkọ oju irin naa. Bakan na ni wọn sọ pe ko saaye fawọn ọlọja rara lati maa ṣe ipolowo ọja wọn ninu ọkọ oju irin naa. Wọn ni oniruuru kamẹra keekeekee lo wa ninu awọn ọkọ oju irin naa, tawọn yoo si fa ẹni to ba jẹbi le awọn agbofinro lọwọ, ki wọn le ba a ṣẹjọ lori ohun to ṣe.
Ọga agba ileeṣẹ to n ri si igboke-gbodo ọkọ niluu Eko, ‘Lagos Metropolitan Area Transport Authority ( LAMATA), Abilekọ Abimbọla Akinajo, lọ sọrọ ọhun di mimọ lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ibudokọ Marina, nipinlẹ Eko. O ni ọkọ reluwee ọhun maa gbera niluu Marina, ti yoo si gunlẹ si Mile 2.
‘Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lo maa kọkọ samulo ọkọ oju irin ọhun, o maa gbera lati ibudokọ Marina lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ. Lẹyin eyi ni awọn araalu maa bẹrẹ si i lo ọkọ oju irin ohun.
Lilọ-bibọ ọkọ oju irin ọhun yoo waye lẹẹmejila lojumọ fun nnkan bii ọsẹ meji pere, ko si ni i pẹ rara ta a fi maa sọ lilọ-bibọ rẹ di mẹrindinlọgọrin lojumọ.
ALAROYE gbọ pe o kere tan, ọkọ oju-irin ọhun yoo maa ko to ero marundinlaaadọsan (175,000) lojumọ.
Siwaju si i, Abilekọ Akinajo ni o yẹ ki ọkọ oju-irin ọhun ti bẹrẹ iṣẹ nibẹrẹ ọdun yii, ṣugbọn awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan tawọn ko lero lo fa idiwọ ọhun.
‘Gbogbo ohun to yẹ pata la ti ṣeto rẹ kalẹ bayii. Ko ni i ju ọsẹ mẹrin lẹyin ta a ba bẹrẹ iṣẹ la maa ṣafikun bi ọkọ naa ṣe maa ṣiṣẹ si laarin ilu.
Mo n rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn ma ṣe gbiyanju lati sọda loju irin naa rara, nitori pe o lewu gidi’.
O ni Naira marundinlẹẹgbẹrin (N750) ni owo tawọn araalu yoo maa san lati ibudokọ Marina si Mile 2. Ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) ni wọn yoo maa san lati Marina si National Theatre, nigba ti wọn yoo maa san irinwo (N400) Naira lati Marina si Iganmu-Orile.
Bakan naa lo fi da awọn araalu Eko loju pe ki ọdun yii too pari, awọn maa ṣe ifilọlẹ ọkọ oju irin ti wọn pe ni Red Line Rail, ta a si maa ṣiṣẹ kaakiri aarin ilu Eko.