Adewale Adeoye ati Jamiu Abayọmi
Titi di akoko ti a n ṣakojọ jọ iroyin yii, inu ahaamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS) ti ọfiisi wọn wa ni Oke-Mọsan, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni alaga kansu ijọba ibilẹ Ijẹbu East, Ọnarebu Wale Adedayọ, to fẹsun kan Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun pe o taari awọn owo to yẹ ko jẹ ti ijọba ibilẹ sibo mi-in tẹnikẹni ko le sọ wa bayii.
Ọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, ni wọn fiwe pe e si ọfiisi wọn ọhun to wa lagbegbe Oke-Mọsan, niluu Abẹokuta, pe ko waa sọ tẹnu rẹ nipa ẹsun ikowojẹ kan to fi kan gomina ipinlẹ naa laipẹ yii.
Ọkan lara awọn ọmọọṣẹ alaga kansu ọhun to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn to ni ki a forukọ bo oun laṣiiri sọ pe oun atawọn kan ti wọn jẹ ọrẹ kori-kosun alaga kansu ọhun lawọn jọ sin alaga naa lọ si ọfiisi DSS, tawọn si pada lẹyin rẹ lẹnu geeti wọn.
ALAROYE gbọ pe lati aarọ kutukutu, ni bii aago mẹsan-an ti Ọnarebu Wale ti wa lọdọ wọn ọhun, wọn ko ti i tu u silẹ, bẹẹ ni wọn ko sọ igba tabi akoko to maa kuro lọdọ wọn.
Ọkan lara awọn mọlẹbi alaga naa ṣalaye pe ilẹ ko ti i mọ tan tawọn ajọ naa ti n fi foonu daamu rẹ lati yọju sawọn, latigba to si ti de sọfiisi wọn, wọn kan lọọ de e mọ’bi kan ni, wọn lawọn ko ti i ṣetan lati ba a lọrọ papọ.
Bẹ o ba gbagbe, Alaga kansu ijọba ibilẹ Ijẹbu East, Ọnarebu Wale Adedayo lo fẹsun kan gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, pe ṣe lo kowo gbogbo ijọba ibilẹ naa to wa nipinlẹ Ogun sapo ara rẹ, ti ko si fawọn lowo to tọ sawọn lati bii ọdun meji sẹyin. O fi kun un pe awọn ẹtọ to yẹ ko maa jẹ toun alaga paapaa ni gomina naa gbẹsẹ le.
Ọjọ keji to sọrọ ọhun lawọn kansẹlọ rẹ yọ ọ danu lẹyin ti wọn fẹsun ikowojẹ kan oun naa. Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni “Gbigba miliọnu mẹrin Naira(N4M) ninu akanti ijọba ibilẹ lati fi ṣe ironilagbara ti ko waye lọdun 2022, fifi owo to n lọ bii miliọnu meji Naira (N2M) ṣofo lori ayẹyẹ ayajọ ọdun Iṣẹṣe tọdun 2022, bibaana ẹgbẹrun lọna ọtalenigba Naira (N260.000) ti alaga ati awọn lọgaalọgaa miiran fi ṣabẹwo sawọn ibi kan l’oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Iwọnyi, atawọn ẹsun ikowojẹ mi-in ni wọn fi kan ọkunrin to ti figba kan jẹ akọroyin, to si tun ba iṣejọba Gbenga Daniel ṣiṣẹ lasiko to wa nipo gomina ipinlẹ Ogun.
Ni bayii, wọn ti ni ki ọkunrin naa ko gbogbo isakoso ijọba ibilẹ naa le igbakeji rẹ lọwọ.