Awọn ọmọ Naijiria yii ti ha siluu oyinbo o, jibiti nla ni wọn lu l’Amẹrika

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ajọ kan to n gbogun ti iwa ibaje lorile-ede Amẹrika, ‘National Crime Agency’ (NCA) ti fọwọ ofin mu awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria mẹta kan ti wọn n gbe nilẹ Gẹẹsi lọhun-un, ṣugbọn ti wọn n lu awọn arugbo kujẹ-kujẹ atawọn abarapa to n gbe nilẹ Amerika ni jibiti owo nla nigba gbogbo. Ẹwọn ọdun mọkanlelogun ni wọn ju awọn mẹtẹẹta  si lẹyin ti wọn ri ẹri to daju pe wọn jẹbi gbogbo ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan wọn patapata.

Awọn mẹtẹẹta ọhun ni: Jonathan Iheanyichukwu Abraham, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, Emmanueli Samuel, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, ati Jerry Chucks, ẹni ọdun mẹtalelogoji.

Lati inu oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, ni ọwọ ajọ NCA ọhun ti tẹ wọn niluu South London, ti wọn n gbe, ko too di pe wọn ṣẹṣẹ dajọ ẹwọn ọlọdun gbọọrọ yii fun wọn lọsẹ yii, lẹyin ti ajọ naa pari iwadii wọn.

Abraham to n gbe lagbegbe Cumberland, Hither-Green, gba idajọ ẹwọn ọdun meje ati oṣu mẹfa, Samuel to n gbe lagbegbe Longhurst, gba idajọ ẹwọn ọdun mẹfa ati oṣu mewaa, nigba ti Ozor to n gbe lagbegbe Wadhurst-Court, gba idajọ ẹwọn ọdun meje ati oṣu mẹta.

ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn ọdaran mẹtẹẹta ọhun ti wọn ti jingiri ninu iwa laabi ọhun maa n kọ lẹta tabi pe sori foonu awọn arugbo ti wọn fẹẹ lu ni jibiti, ti wọn yoo si sọ fun wọn pe mọlẹbi wọn kan to ku laipẹ fi gbogbo owo rẹ to wa ni banki awọn lorileede Spain silẹ fun wọn. Ṣugbọn wọn ni lati kọkọ sanwo kekere kan fawọn, kawọn ba wọn fi to iwe, ki owo ọhun le tete jade si wọn lọwọ pẹlu irọrun.

Bakan naa ni awọn ẹlẹgbẹ wọn kọọkan ti wọn n gbe lorileede Spain ati Portugal paapaa a maa pe onitohun pe loootọ ni ohun tawọn to n gbe lorileede Gẹẹsi ọhun n ba wọn sọ.

Ajọ NCA ọhun ni pẹlu iranlọwọ awọn alaṣẹ ilẹ Spain ati ti Portugal, ọwọ awọn ti tẹ awọn agbodegba awọn ọdaran ọhun, ti gbogbo wọn pata si ti n sọ ipa ti wọn ko ninu iṣẹ laabi ọhun.

Wọn ni awọn ṣi n ṣewadi awọn agbodegba tọwọ tẹ niluu Madrid, nilẹ Spain, lọwọ, ati pe ninu oṣu Kẹwaa ọdun yii, lawọn maa too ṣedajọ gbogbo wọn pata.

Leave a Reply