Iru ki waa leleyii, awọn agbebọn paayan meje sinu mọṣalaṣi lasiko ti wọn n kirun lọwọ

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ ọhun di bo o lọ o ya fun mi lakooko tawọn agbebọn kan ti ko sẹni kan to mọ ibi ti wọn ti wa deede ṣina ibọn bolẹ fawọn olujọsin mọṣalaṣi kan to wa lagbegbe Saya-Saya, nijọba ibilẹ Ikara, nipinlẹ Kaduna lọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe irun alẹ ti wọn n pe ni Ishai ni wọn n ki lọwọ ninu mọṣalaṣi nla naa ko too di pe awọn agbegbọn ọhun ti wọn pọ niye ṣina ibọn fawọn ti wọn ba lẹnu irun ọhun, ti wọn si paayan marun-un danu loju-ẹsẹ, ko too tun di pe wọn lọọ yinbọn pa awọn meji miiran lagbegbe kan ti ko fi bẹẹ jinna rara si mọsalaṣi ọhun.

Lara awọn olujọsin to ba iṣẹlẹ laabi ọhun lọ ni olori awọn fijilante adugbo naa.

Alahji abdulraman Yusuf ti i ṣe olori ilu naa to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin sọ pe ni aṣaalẹ ọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, ni iṣẹlẹ buruku ọhun ṣẹlẹ, ati pe ko sẹnikankan to mọ orukọ awọn ẹni to ba iṣẹlẹ ọhun lọ lakooko ta a n kọ iroyin yii lọwọ nitori pe loju-ẹsẹ ni wọn ti sinku wọn ni ilana ẹsin Islam.

‘Ohun ti mo ro ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn agbebọn ọhun tọ ipasẹ olori fijilante ọhun wa sinu mọṣalaṣi naa ni, nitori pe ko pẹ rara to darapọ mo awọn olujọsin inu mọṣalaṣi naa  ni awọn agbebọn ọhun de, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ fawọn to n kirun lọwọ, olori figilante naa si wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ bayii’.

Eeyan marun-un lo ku, bakan naa ni dẹrẹba kan to gbe ounjẹ wa si mọṣalaṣi ọhun wa lara awọn to padanu ẹmi wọn lọjo naa.

Ṣao olori ilu ọhun ni awọn alaṣẹ ijọba ti bẹrẹ si i pese aabo to peye fawọn araalu naa bayii, kiru ohun to ṣẹlẹ naa ma baa waye mọ rara.

Ọgbẹni Mansir Alhassan ti i ṣe adele ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa loun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ abẹnu, ti wọn si maa too fọwọ ofin mu awọn ọdaran naa laipẹ yii.

Leave a Reply