Monisọla Saka
Gbajugbaja oṣere-kunrin ilẹ wa ti awọn obi rẹ naa jẹ oṣere, Muka Ray Eyiwumi, ti dide iranwọ fawọn eeyan ilu ẹ, nitori bi ara ṣe n kan awọn eeyan lẹyin tijọba fopin si owo iranwọ ori epo mọ.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni ọkunrin ọmọ bibi ilu Àrán-Ọ̀rin, nipinlẹ Kwara, to tun jẹ oludamọran pataki fun Gomina Abdulrazak, gba awọn ilu bii Ipetu, Rorẹ́, ati Aran Ọ̀rin, to wa nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara lọ.
Awọn ounjẹ tutu atawọn ohun eelo amaratuni mi-in bii apo raisi nla lọpọlọpọ. apo ẹwa nla, apo nla nla ti wọn di gaari si, ọpọlọpọ iṣu, paali ounjẹ igbalode Indomie, ẹrọ ata, ẹrọ iranṣọ, epo pupa, ibusun oni timutimu (mattress), ororo ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni wọn pin fun awọn araalu naa.
Lasiko to n ba awọn ti wọn janfaani eto naa sọrọ, Ọnarebu Muka Ray ni gbogbo nnkan toun ṣe yii, nitori Gomina Abdulrahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ni, nitori gudugudu meje to ti n ṣe latigba ti ọrọ owo epo ti bẹrẹ, ti gbogbo nnkan si ti gbowo lori, loun ṣe ronu nnkan toun le fi kun ijọba ipinlẹ Kwara lọwọ lati le mu adinku ba inira araalu.
O ni, “Nnkan to foju han, ti odi paapaa si n gbọ ketekete, ni pe gomina mi daadaa, Ọlọla ju lọ, Gomina Abdulrahman AbdulRazaq, n mu igbaye-gbadun awọn eeyan ipinlẹ Kwara ni ọkunkundun gidi gan-an ni. Eyi ko ṣai foju han ninu gbogbo awọn igbesẹ ti ki i fi falẹ ti wọn maa n gbe lati le din iṣẹ ati iya ti owo iranwọ epo ti ijọba ko san mọ ko ba gbogbo ilu ku. Oriṣiiriṣii eto atawọn nnkan ti yoo din inira ku ni ijọba ti pese silẹ ni sẹpẹ lati mu ki ara tu tolori tẹlẹmu.
Amọ ṣa o, eyi ti mo ṣe yii ki i ṣe lati da ijọba lagara tabi lati fi tẹ wọn. A ṣe e lati fi ran ijọba lọwọ lori gbogbo eyi ti wọn n ṣe lati mu ki ara tu awọn eeyan ipinlẹ wa ni”.
Bakan naa ni Muka Ray tun rọ awọn eeyan lati gbaruku ti ijọba, ki wọn ma si ṣe wo gbogbo inira ti wọn n la kọja lọwọ bayii, bi ko ṣe ohun rere ti irora oni yoo bi lọjọ ọla fun gbogbo wa.