Muri Thunder pada sọdọ Saheed Oṣupa, o ko si Oufimọ, ko si orin

Olubukọla Ganiu

Aawọ atọdunmọdun to n bẹ laarin agba olorin Fuji nni, Saheed Oṣupa, ati ọkan lara awọn ọmọ ẹyin ẹ to fẹran daadaa, Muri Alabi Thunder, ti pada pari bayii.

Ninu fọnran kan ti Saheed gbe sori Instagraamu Saheed lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Muri Thunder ti wọn tun maa n pe ni Awoko olorin ti waa tuuba nile ọba orin.

O ni oun ri gbogbo awọn iwa oun latẹyinwa gẹgẹ bii aṣiṣe, ati pe ọmọde lo ṣe oun, nitori ọmọde ko le mọ ẹkọ ọ jẹ ko ma ra a lọwọ.

O ṣalaye siwaju si i pe nnkan toun mọ to daju, ti ko si ruju ni pe ọba orin ni Saheed. O ni koda ni gbogbo igba toun ṣáko lọ, oun mọ pe ibi ti Saheed ba wa, orin wa nibẹ, nibi ti wọn ko ba si ti ri Saheed, ki wọn gbagbe ẹ, ko si orin kankan nibẹ.

Nibi yii lo sọrọ de ti Saheed fi bi i pe ko tun un sọ, ati pe ṣe nnkan to sọ da a loju, nitori oun Saheed kọ loun sọ bẹẹ o.

Muri ni bẹẹ ni, ọrọ toun si ti sọ ri lori eto ori redio kan ni paapaa. O ni ko sẹni ti ko mọ pe yala wọn ṣe igbaradi tabi eyi ti wọn ko palẹmọ fun, Saheed ko ni i kalolo, bẹẹ ni ko ni i fikan pe meji bi orin ba ko si i lẹnu.

O ni nitori naa, oun gba fun ọga oun, oun si ti dari wale pada, ki wọn fori ji oun, ki Saheed gbagbe ọrọ ana, ko si da oun pọ mọ awọn yooku tọ.

Oṣupa tun bi i leere pe oun ṣe rẹkọọdu kan nigba kan, bo ṣe gbe orin ọhun ni Muri Thunder naa fi ẹnu si i, o ni,

“Ta a ba n ba a sọrọ o yẹ ko maa gbọ

Ta a ba n ba a sọrọ o yẹ ko maa gbọ.

Tori ẹrú to ba gbọ tolowo ẹ aa f’ẹran j’iyan

Eyi ti o gbọ tolowo ẹ aa jiyan lasan

Ta a ba n ba a sọrọ o yẹ ko maa gbọ”.

O waa bi Muri Thunder pe ṣe o ranti, Muri ni oun ranti daadaa. Saheed ni Muri gan-an loun n forin naa ṣekilọ fun lọjọ naa lọhun-un, oun si mọ pe yoo gbọ ọ nigba to jade.

Saheed waa fi ọrọ pa aṣamọ bo ṣe jẹ pe imọran odi ti Muri gba lo gbe e kọ lu oun. O ni oriṣiiriṣii lawọn eeyan, oniruuru ọna si ni wọn n gba lo imọran ti wọn ba fun wọn.

O ni nigba tawọn mi-in n lo ọgbọn ọlọgbọn fi ṣọgbọn lai ro o lẹẹmeji, awọn kan maa n powe dan an wo lo bi iya ọkẹrẹ funra wọn ni, nigba ti wọn ba kuna, to ja jo wọn loju, ni wọn yoo ṣẹṣẹ waa ṣamulo imọran ti wọn ba fun wọn.

Nibi ni Saheed sọrọ de ti ọkan lara awọn ọmọ abẹ Saheed ti wọn maa n pe ara wọn ni mọlẹbi Olufimọ fi mu orin bọnu, to ni ko si bi ọmọde ṣe le gbọn to, iwaju ni yoo maa tọ ti agbalagba, o lohun ti agba ri lori agbantara, bọmọde gun igi iroko ko le ri i, bẹẹ ni ohun ti agbalagba ri ti oju ẹ fi jin sinu, bọmọde ba ri i, raurau loju naa yoo fọ. O forin powe fun Muri pe ọga lọga yoo maa jẹ lọjọkọjọ, ọmọ ẹyin to ba si gbafa fun ọga ko ni ṣai ri èrè jẹ. Bẹẹ lo rọ Saheed naa lati fa a mọra, ki idagbasoke le tubọ maa lọ laarin awọn mọlẹbi Olufimọ.

Muri Thunder tẹriba, o si wọ ọga rẹ mọra pe oun ti gba pe oun ṣe aṣiṣe, oun si ti pada sile toun ti sa kuro lati ọjọ gbọọrọ. Pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn eeyan wọn yooku ti wọn peju sinu ile naa fi ho fun ayọ.

Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ti Muri Thunder to jẹ ọkan lara awọn to ti ara Saheed goke ya kuro lọdọ ọga ẹ pẹlu iru ifẹ to ni si i to, ni Safẹjọ Amama naa lọ, to fi kan Kòkòrò Taofiki, eebu atawọn ọrọ kobakungbe ni wọn si maa n ran si Saheed ni gbogbo igba naa. Wọn ni ọlọtẹ ni, nitori bẹẹ si ni gbogbo awọn ọmọ ẹ ṣe n sa lọ fun un.

Gbogbo awọn alatilẹyin, ololufẹ alaafia ati ti Saheed paapaa ni wọn fi idunnu wọn han nigba ti wọn ri fidio naa. Wọn ni bo ṣe yẹ ko ri naa niyẹn, pe afi ki agba Saheed gba gbogbo ẹ mọra. Wọn ni inu awọn dun si ohun to ṣẹlẹ naa, ohun ayọ bayii ni yoo si maa ṣẹlẹ lagboole Olufimọ Ọba orin kaafata.

 

Leave a Reply