Nitori ibasun, Aminu lu iyawo ẹ pa

 Jamiu Abayọmi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti mu ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan, Aminu Mahdi, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o lu iyawo rẹ, Hadiza Zubuchi, ẹni ọdun mẹtalelogoji, titi tẹmi-in fi bọ lara rẹ, o ni iyawo oun ko jẹ ki oun ba a sun loun kuku ṣe ṣeku pa a.

ALAROYE gbọ pe oṣiṣẹ-fẹyinti lẹka eto ẹkọ, iyẹn Adamawa State Universal Basic Education Board (ADSUBEB), lọkunrin to lu iyawo rẹ pa ọhun.

Awọn ọlọpaa fidi ẹ mule pe abule kan ti wọn n pe ni Yelwa, nijọba ibilẹ Ariwa Mubi, nipinlẹ naa ni iṣẹlẹ laabi ọhun ti waye l’ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii.

Ninu ọrọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Suleiman Nguroje, lo ti fidi ẹ mulẹ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an yii lọwọ too ba ọkunrin ọhun, to si ti jẹwọ pe oun loun ran iyawo oun naa nirinajo aremabọ, toun ṣeku pa a.

Nigba ti Aminu n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye lo ti sọ bayii pe, “Mo de lati ode ti mo lọ lalẹ ọjọ naa ni nnkan bii aago mẹsan-an, lẹyin ti mo jẹun alẹ tan ti mo si wọle tọ iyawo mi lọ pe ki a ṣe ‘kinni’, lo ba kọ fun mi lati ṣe bẹẹ.

“O bẹrẹ si i fi igi nla kan lu mi leralera, to si n pariwo pe ki n jade ninu yara oun, ṣugbọn mo pada ri igi naa gba lọwọ rẹ, mo si fọ mọ ọn lori titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

“Ohun ti mo ṣe naa dun mi pupọ pe ọwọ mi ni ẹmi ọmọbinrin naa ti bọ, ti mo si da ara mi lẹbi lori iwa ti mo hu naa, nitori pe lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2016, la ti fẹra wa”.

Ọga ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Afọlabi Babatọla, ti paṣẹ pe ki awọn gbe ọkunrin naa lọ si ẹka to n wadii iwa ọdanran, Criminal Investigation Department (CID), fun iwadii to peye lori iṣẹlẹ naa, lẹyin iwadii ni yoo foju ba ile-ẹjọ, nibi ti yoo ti gba idajọ ẹṣẹ rẹ.

Leave a Reply