Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Ọga awọn aṣọbode to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, CSC Shehu Minna, ti parọwa sawọn ọdọ ilu Ṣaki tinu n bi lakooko akọlu to waye lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun yii, pe ki wọn jọwọ, ba awọn da ibọn ijọba to wa lọwọ wọn pada.
O parọwa yii lakooko tawọn ẹgbẹ akọroyin ipinlẹ Ọyọ, eyi ti alaga wọn, Kọmureedi Demọla Babalọla, ko sodi lati lọọ ba ileeṣẹ kọsitọọmu naa kẹdun lori iṣẹlẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, ọsan ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, to kọja yii, niṣẹlẹ buruku naa waye, nigba ti ọkan lara awọn ọdọ ilu naa padanu ẹmi rẹ nibi ti aawọ kan ti waye laarin awọn aṣọbode atawọn onifayawọ. Iṣẹlẹ yii lo mu ki awọn ọdọ ilu naa fariga, ti wọn lọọ fibinu gbẹsan ohun to ṣẹlẹ naa, ti wọn pa aṣọbode ti wọn ba lọọfiisi wọn, wọn dana sun ọfiisi naa, wọn si tun gbe ibọn ti wọn fi n ṣiṣẹ lọ titi doni.
Alaga ẹgbẹ awọn akọroyin naa ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bii eyi to buru jai, o ni ohun ti ko yẹ ko waye rara ni, lẹyin eyi lo parọwa si ọga aṣọbode naa pe ko ṣeto lati jẹ ki asọye maa wa laarin awọn oṣiṣẹ rẹ ataraalu, eyi to ṣee ṣe ko dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
CSC Shehu Minna waa gboriyin fun ẹgbẹ awọn akọroyin orileede yii, paapaa ẹka ti ipinle Ọyọ. O ni wọn ni iṣẹ ribiribi lati ṣe lati jẹ ki awọn araalu mọ ojuṣe wọn nipa lila wọn lọyẹ lori ofin tijọba fi de kiko ẹru ti ko bofin mu wọle si orileede yii, yala lori ilẹ, ori omi, ati oju ofurufu.
O ni iṣẹ awọn aṣọbode faaye silẹ fun ifikunlukun lati jiroro lori bi ijọba yoo ṣe pa owo wọle lati ara sisan owo-ori ọja gbogbo.
Ọkunrin yii ni idi toun fi pariwo sita lori ibọn to wa nikaawọ awọn ọdọ wọnyi ni pe awọn oloṣelu le lo awọn ọdọ wọnyi ati ibọn naa fun ete imọtara-ẹni-nikan, tabi ki wọn lọọ fi ibọn naa jale nibikan, eyi si maa ṣakoba fun ileeṣẹ kọsitọọmu ati orukọ rere rẹ. O waa rọ awọn oniroyin lari parọwa sawọn ọdọ ọhun lati da ibọn to wa lọwọ wọn pada, tori ole to gbe kakaaki ọba lọrọ naa jẹ fun wọn, ko si ibi ti yoo ti fọn ọn.