Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bo ṣe fi oju ọla awọn ọba agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, gbolẹ, ẹgbẹ kan niluu Iṣẹyin, ti wọn n jẹ Ẹbẹdi Frontliners, Iṣẹyin (EFI), ti sọ fun aarẹ orile-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati tete tọrọ aforiji lọwọ awọn ọba to wa lapa Oke-Ogun, bi bẹẹ kọ, ko ma de ilu awọn mọ laelae.
Ninu atẹjade kan ti Igbakeji Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Bambi Abiọdun ati Alukoro rẹ, Alaaji Ṣẹgun Fasasi, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Kẹsa-an, ọdun yii, ni wọn ti sọrọ naa.
Wọn ni ko yẹ ki iru ọrọ ti Ọbasanjọ sọ yii jade lati ẹnu agbalagba Yoruba, paapaa, ẹni to tun jẹ oloye nilẹ Yoruba, nitori o ti fẹnu yẹpẹrẹ awọn ọba ilẹ Yoruba kaakiri agbaye.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ninu atẹjade naa, “Lorukọ awa ọmọ ilẹ Yoruba tootọ, a n fi asiko yii sọ fun aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati yaa tete tọrọ aforiji lọwọ awọn ọba wa lapa Oke-Ogun, fun awọn ọrọ arifin to sọ si wọn nigba to sọ pe wọn kuna lati dide ki oun ati gomina lasiko ti awọn fẹẹ lọọ sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ẹka iṣẹ ọgbin nileewe LAUTECH, to wa niluu Iṣẹyin.
“Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nigba ti Ọbasanjọ ati gomina de sibi ayẹyẹ yii, ṣe ni gbogbo eeyan dide ki wọn gẹgẹ bii ami ibu ọla fun ni, wọn si tun ṣe bẹẹ nigba ti wọn fẹẹ lọọ sọrọ, eyi lo ṣe ya wa lẹnu bi Ọbasanjọ ṣe n jagbe mọ awọn ọba wa bii ọmọ ileewe alakọọbẹrẹ.
“A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe pẹlu iwa ti Ọbasanjọ hu yii, a fẹ ko tọrọ aforiji kiakia, bi bẹẹ kọ, a ko fẹẹ ri ẹsẹ rẹ ni agbegbe kankan lapa Oke-Ogun mọ.”
Tẹ o ba gbagbe, niluu Isẹyin, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an yii, l’Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba agbegbe naa pe ki wọn dide, ki wọn jokoo, bii igba ti awọn olukọ ba n paṣẹ fun awọn ọmọ jẹle-o-sinmi nileewe.