Ibrahim Alagunmu n’llọrin
Ọmọkunrin kan, Tashiu Aminu Lulu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ni igbadun iṣẹju kan, yunkẹyunkẹ takọ-tabo ẹẹkan ṣoṣo ti ran lẹwọn bayii. Adajọ ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Kaiama, nipinlẹ Kwara ti sọ ọ sẹwọn ọdun marun-un. Ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Halirat Ismail, lo fipa ba lo pọ logunjọ, oṣu Kẹsan-an yii, niluu Woro, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara.
Alukoro ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ naa, Ayẹni Ọlasunkanmi, sọ fun ALAROYE, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, pe ọmọbinrin kan, Halirat Ismail, lo mu ẹsun lọ si ọfiiṣi ajọ naa pe Tashiru Aminu, lo pe oun lori ẹrọ ibaniṣọrọ pe ki oun wa kiakia, ṣugbọn bi oun ṣe dele rẹ lo ni ki oun bọ aṣọ silẹ nihooho, o mu buleedi, o fi fa irun abẹ, ori ati abiya oun. Lẹyin naa lo gbe igba kan fun oun to n pọfọ si, ko too ṣẹṣẹ waa ba oun laṣepọ karakara, toun ko si gbadun mọ latigba naa, to jẹ pe alakalaa loun kan n la bayii.
Ayẹni tẹsiwaju pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, afurasi jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọbinrin naa sun, eyi lo mu ki ajọ ṣifu difẹnsi taari rẹ lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Kaiama.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Abubakar Ahmed Boro, da afurasi naa lẹbi lori ẹsun kin-in-ni, eyi ti i ṣe nini ibalopọ aitọ pẹlu ọdọbinrin, o si ni ko lọọ lo ọdun meji lẹwọn. Ẹsun keji ni lilo oogun abẹnugọngọ, o ni ko lọọ lo ọdun mẹta lẹwọn. Lo ba ni ko tete lọọ fẹwọn ọdun marun-un jura pẹlu iṣẹ aṣekara.