Awọn ẹlẹrii Mohbad yoo yọju sile-ẹjọ

Jamiu Abayọmi

Igbimọ awọn adajọ ti wọn gbe kalẹ lati ṣewadii akanṣe nipa iku ọdọmọde olorin ilẹ wa nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ tun mọ si Mohbad (Coroner’s inquest), ti ranṣẹ pe awọn ẹlẹrii ti wọn yoo waa jẹrii nipa ohun to ṣokunfa iku ọmọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Imọlẹ, to jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an to ṣẹṣẹ pari yii. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa, ọdun yii ni ijokoo naa yoo waye.

Nibi ijokoo iwadii to waye nile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni wọn ti ṣiṣọ loju ọrọ naa.

Funmi Falana to jẹ iyawo agbẹjọro agba ati ajafẹtọọ ọmọniyan ilẹ wa nni, Fẹmi Falana, atawọn lọya mi-in ni wọn ṣoju mọlẹbi Mohbad nibi ijokoo ipade atilẹkun mọri ṣe ọhun, nibi ti wọn ti jiroro lori awọn eto ati igbesẹ ti wọn yoo gun le lati ṣagbejade awọn ẹri ti wọn yoo lo lori iwadii iku Mohbad ni kootu Candide Johnson, to wa lagbegbe Owolowo, niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade naa, Funmi Falana sọ pe, “Ohun ti a ṣe lonii ni pe a ṣe ipinnu lori igba ati ọna ti a maa gba ti awọn ilana ti a gbe kalẹ maa fi ran wa lọwọ lati ri idajọ ododo. A ti mu ọjọ bayii, a oo si ṣafihan awọn ẹlẹrii wa.

O fi kun un pe kawọn eeyan ni ireti lori pe idajọ ododo yoo tibẹ wa, nitori pe awọn gan-an wa lori ipinnu ati ri idajọ ododo lori iku oloogbe naa.

“A wa nibi lati duro fun idajọ ododo ni, a dẹ ni lati jẹ ki alaafia jọba, ṣugbọn idajọ ododo gbọdọ jọba, a maa mọdi iku oloogbe naa.”

Lati igba ti Mohbad ti jade laye ni gbogbo eeyan ti fẹẹ mọdi iku to pa a, ti sinsin oku rẹ lọjọ keji iku rẹ to jẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ojọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an to kọja yii, paapaa tun fẹẹ mu ifura lọwọ. Eyi lo fa a ti iwadii fi bẹrẹ ni kiakia, ti igbimọ ẹlẹni mẹtala ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣagbekalẹ rẹ si ti n ṣaṣeyọri bọ debi to de duro bayii.

Awọn ikọ agbẹjọro fun mọlẹbi oloogbe ati igbimọ oluwadii ti waa panu-pọ bayii, wọn si ti mọjọ ti ẹlẹrii yoo fara han lori iku oloogbe naa.

Leave a Reply