Faith Adebọla
Latari awuyewuye to n waye lori abọ iwadii awọn iwe-ẹri Aarẹ orileede wa, Bọla Ahmed Tinubu, eyi ti Atiku Abubakar tori rẹ pẹjọ sorileede Amẹrika pe ki wọn ko awọn iwe-ẹri ọkunrin naa foun lati ṣayẹwo rẹ, Fasiti ipinlẹ Chicago, iyẹn Chicago State University, CSU, ti fidi ẹ mulẹ pe ni tododo, Bọla Tinubu kawe, o si gboye jade nileewe giga naa.
Eyi wa ninu ibura labẹ ofin ti Akọwe kan lọfiisi fasiti ọhun, Ọgbẹni Caleb Westberg, ṣe lori awọn akọọlẹ ati ẹda iwe-ẹri ti Fasiti Chicago naa ko fun Atiku Abubakar nipasẹ lọọya rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, lọfiisi agbẹjọro Atiku, Abilekọ Angela Liu, eyi to wa ni ọna West Wacker Drive, niluu Chicago, l’Amẹrika.
Niṣeju awọn lọọya marun-un mi-in lati ileeṣẹ Dechert LLP, nibura ọhun ti waye. Wọn ni, lai fọrọ bọpo bọyọ, Bọla Ahmed Tinubu kawe nileewe naa lati oṣu Kẹjọ, ọdun 1977, si oṣu Kẹfa, ọdun 1979, awọn si fun un niwee-ẹri oye imọ okoowo ṣiṣe, Bachelor of Science in Business Administration, with Honors. Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 1979, ọhun lo gba iwe-ẹri naa.
Akọsilẹ ati ẹri ti aṣoju fasiti yii jẹ ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni Aarẹ Tinubu lọ si Fasiti Chicago. Ṣugbọn kan ṣoṣo to wa ninu iwe-ẹri ti Tinubu gba jade ni pe ki i ṣe ojulowo iwe-ẹri to gba jade gan-an lo ko silẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa nigba to fẹẹ dupo aarẹ. Ayederu pata gbaa to yatọ si eyi ti fasiti naa n fun awọn akẹkọọ to ba yege nileewe rẹ lo fi silẹ.
Oluranlọwọ pataki si Atiku Abubakar lori eto ibanisọrọ, Ọgbẹni Phrank Shaibu sọ lọjọ Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa yii pe:
“Awọn ẹda iwe-ẹri Tinubu ti Fasiti Chicago ko fun wa ti fihan pe ayederu iwe-ẹri leyi ti to ko kalẹ fun INEC. Kedere laṣiiri naa foju han lasiko ti aṣoju CSU n ṣebura lori awọn iwe-ẹri naa lọjọ Tusidee ọhun’’.
Nigba ti wọn ṣe ayẹwo finni-finni si ẹda sabukeeti Fasiti Chicago ti Tinubu fun INEC, paali naa ko dọgba pẹlu eyi ti fasiti naa mu jade gẹgẹ bii ojulowo tawọn fun Tinubu tẹlẹ.
Lara iyatọ ibẹ ni pe ibuwọluwee Aarẹ fasiti naa, Elnora D. Daniel, ati ẹnikeji rẹ, Dokita Niva Luben, ki i ṣe ojulowo, nitori I996 ati I998 lawọn mejeeji yii di aarẹ ati ọmọ igbimọ aṣeefọkantan (Board of Trustee) Fasiti Chicago, igba naa si ni wọn too laṣẹ lati buwọ lu sabukeeti lorukọ ileewe naa, bẹẹ ọdun 1979 ni Tinubu ti gba sabukeeti rẹ.
Yatọ siyẹn, labẹ ami ileewe naa, tawọn eleebo n pe ni logo wọn, wọn kọ 1867 sibẹ, amọ ko si ohun to jọ bẹẹ ninu eyi ti Tinubu ko fun INEC.
Lafikun, ‘With Honors’ fara han ninu sabukeeti ti INEC ni Tinubu fun awọn lasiko ibo, amọ ko sohun to jọ bẹẹ ninu eyi ti Fasiti Chicago fun Atiku, ko si sohun to jọ bẹẹ ninu awọn sabukeeti mi-in ti wọn tẹ jade lasiko ọhun fawọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ.
Shaibu ni ọpọ magomago lo ṣẹlẹ ninu akọọlẹ Tinubu ni fasiti ọhun, o ni gbogbo rẹ lawọn yoo si foju rẹ hande laipẹ.