Lori iku Mohbad: Awọn ọlọpaa ti mu Naira Marley

Faith Adebọla

Afaimọ ni ki i ṣe orin ‘kaabọ, ṣe daadaa lo de, a ti n reti rẹ’ lawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko fi ki Afeez Faṣọla, tawọn eeyan mɔọ si Naira Marley kaabọ lati ilu oyinbo to ti n bọ, pẹlu bawọn agbofinro ọhun ṣe gan an lapa lati papakọ ofurufu Muritala Mohammed to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ ọhun, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 yii, ti wọn si fi pampẹ ofin mu un lọ sakolo wọn.

Eyi ko ṣẹyin iwadii ijinlẹ ti ikọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ẹlẹni mẹtala kan ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko gbe kalẹ lọsẹ meji sẹyin n ṣe lati tuṣu desalẹ ikoko,  ki wọn si wa fin-in idi koko iṣẹlẹ iku ojiji to pa gbajugbaja olorin taka-sufee nni, Oloogbe Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si MohBad.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin lo sọrọ yii di mimọ loju opo Twitter rẹ ti wọn n pe ni X bayii. O kọ ọ sori ẹrọ ayelujara ọhun pe:

“A ti mu Azeez Faṣọla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Naira Marley, a si ti mu un lọ si akata awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii ati ibeere gbogbo to tan mọ ohun ta a n wadii rẹ.” Ọrọ ṣoki to sọ ọhun ko ju bẹẹ lọ.

Iwadii ALAROYE fihan pe nnkan bii aago mẹsan-an ku ogun iṣẹju lalẹ ọjọ Tusidee ọhun ni Naira Marley sọkalẹ ninu baaluu to gbe e gunlẹ si papakọ ofurufu n’Ikẹja, ko si ju iṣẹju diẹ lẹyin naa tawọn ọlọpaa ti wọn ti n duro de e mu un lọ taara sinu ọkọ wọn, ti wọn si gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ itọpinpin wọn to wa ni Panti, lagbegbe Yaba, ibẹ ni igbakeji Kọmiṣanna, DCP Waheed Ayilara, ti ki i kaabọ, ti wọn si jọ wọnu ile lọ.

Ki wọn too mu un ni ọkunrin tawọn eeyan n fẹsun hihuwa aidaa si Mohbad kan ọhun ti kede ipadabọ rẹ si Naijiria loju opo ayelujara tuita rẹ lọjọ Tusidee naa, o ni tori koun le ran awọn ọlọpaa lọwọ lori iwadii iku Mohbad ti wọn n ṣe loun ṣe de, o ni inu oun dun si ki idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ ọhun.

Ẹ oo ranti pe ọkunrin yii, ati ọrẹ rẹ kan, Sam Larry, iyẹn Samson Balogun Eletu, wa lara awọn afurasi ti ẹnu n kun gidi lori iku ojiji to pa oloogbe Mohbad. Latigba tiṣẹlẹ buruku ọhun ti waye lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, to kọja yii, lọpọ awuyewuye ti gba igboro kan lori ohun to ṣokunfa iku aitọjọ naa, tori ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn pere ni oloogbe yii. Asiko ti irawọ rẹ si n tan ni oṣupa onkọrin naa wọọkun lojiji. Latigba naa lawọn eeyan kan ti pariwo ki wọn mu Naira Marley, ki wọn mu Sam Larry lori ẹrọ ayelujara.

Amọ ṣa o, Naira Marley ti sọ ninu awọn fidio kan pe ọwọ oun ko si nidii iku oloogbe yii, o ni ọtọ ni ibi ti iku ẹ ti wa.

Leave a Reply