Ọrẹ Mohbad tawọn ọlọpaa n wa ti jọwọ ara rẹ fun wọn o

Adewale Adeoye

Ni bayii, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe gbajumọ olorin takasufee nni, Owodunni Ibrahim ẹni tawọn eeyan mọ si Primeboy tawọn ọlọpaa kede rẹ pe awọn n wa lori iku oloogbe Mohbad ti jọwọ ara rẹ silẹ fawọn tawọn si ti ju u sahaamọ awọn ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Wọn lawọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ lopin iwadii tawọn n ṣe lori ohun to mọ nipa iku oloogbe naa.

Awọn ọlọpaa kede Primeboy to jẹ ọrẹ korikosun oloogbe naa gẹgẹ bi ọdaran lẹyin to kuna lati jẹ ipe wọn lẹyin ti wọn fiwee pe e pe ko waa sọ tẹnu rẹ lori ohun to mọ nipa iku oloogbe naa. Primeboy yii l’awọn eeyan sọ pe, o jẹ ọrẹ ati kekere oloogbe naa ati pe ọwọ rẹ ko mọ rara lori iku to pa Mohbad.

Ẹbun miliọnu kan naira ni ọga agba ọlọpaa patapata nipinlẹ Eko, C.P Idowu Owohunwa nileeṣẹ ọlọpaa maa fẹni iyoowu to ba le ran awọn lọwọ lati fọwọ ofin mu Primeboy ti wọn funra si pe o lọwọ ninu iku oloogbe naa. Ọjọ keji ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi ọdaran tawọn ọlọpaa n wa loun paapaa ti lọọ jọwọ ara rẹ silẹ fun wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko S.P Benjamin Hundeyin to fidii iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lori ẹrọ ayelujara rẹ sọ pe funra Primeboy lo waa jọwọ ara rẹ silẹ fawọn ọlọpaa lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi ọdaran tawọn ọlọpaa n wa laarin ilu.

‘Oju-esẹ tawọn ọlọpaa ti gba a mu ni wọn ti bẹrẹ si i beere ọrọ lọwọ rẹ nipa ohun to mọ nipa iku oloogbe naa’.

Siwaju si i, alukoro ni ọga agba patapata tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, C.P Idowu Owohunwa lawọn maa ṣiṣẹ iwadii awọn daadaa tawọn si maa f’ọwọ ofin mu gbogbo awọn ẹni to ba lọwọ ninu iku oloogbe naa pata ki wọn le jiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe. Ko si tun le jẹ ẹkọ nla fawọn oṣika gbogbo pe iwa laabi ko daa.

Bẹẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii ni oloogbe Ilerioluwa Alọba ẹni tawọn eeyan mọ si Mohabd ku ṣugbọn tawọn eeyan naka aburu si Naira Marley ti i ṣe ọga rẹ tẹlẹ. Naira Marley ati Sam Larry tawọn araalu naka aburu si pe ọwọ wọn ko mọ lori iku oloogbe naa lo jẹ pe ṣe ni wọn funra wọn jọwọ ara wọn silẹ fawọn ọlọpaa. Lẹyin tawọn ọlọpaa f’ọwọ ofin mu wọn tan ni wọn ṣẹṣẹ too kede pe ki Primeboy ti i ṣe ọrẹ korikosun oloogbe naa yọju s’àwọn ọlọpaa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Eko. Lẹyin to taku, ti ko lọọ b’awọn ni wọn ba kede rẹ gẹgẹ bi ọdaran tawọn ọlọpaa n wa.

Leave a Reply