Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi dasiko yii ni iku ọmọdebinrin kan, Fathia Ọjẹwoye, ti ọjọ ori ẹ ko ju mẹrinla lọ ṣi n jẹ ijọloju fawọn eeyan laduugbo Pepsi, Quarry ati Ori Iyanrin, l’Abẹokuta. Idi ni pe ko ṣaarẹ, awọn eeyan ṣi ri i daadaa titi di irọlẹ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an yii, to di awati, to si waa jẹ pe oku ẹ ni wọn ri lọjọ kẹta ti wọn ti n wa a.
Gẹgẹ bi AKEDE AGBAYE ṣe gbọ, gaasi idana ni Iya Fathia ni ko lọọ ṣafikun ẹ wa ni Quarry Road. O ti fiili gaasi ọhun tan, o si gbe e sẹnu ọna fun mama rẹ.
Bo ṣe gbe gaasi naa silẹ tan ni wọn lo pada lọọ ba ọkunrin nisalẹ, ọkunrin naa lo si ba lọ ti wọn ko fi ri i mọ.
Ẹni to ṣalaye ọrọ naa fun wa sọ pe Fathia ko mọ ọkunrin naa ri, o jọ pe ẹni naa fi oogun ba a sọrọ pe ko lọọ gbe gaasi silẹ ko waa ba oun nisalẹ kawọn jọ maa lọ ni.
Nigba ti mama rẹ ri gaasi ti ko ri ọmọ lo bẹrẹ si i pe e kiri ile, awọn eeyan to ri i nigba to n ba ọkunrin naa lọ ni wọn sọ fun iya rẹ pe awọn ri i ti ọkunrin kan fa a lọwọ ti wọn jọ n lọ. Bo ṣe di pe wọn bẹrẹ si i wa a niyẹn lati irọlẹ ọjọ naa.
Wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, awọn sọ pe ko sohun tawọn le ṣe si i, afi to ba pe wakati mẹrindinlogun ti wọn ko ti ri i.
Nigba ti ọjọ kan tawọn ọlọpaa sọ yii pe ti wọn ko tun ri i, wọn kede ẹ pe awọn n wa a, gbogbo agbegbe Ori Iyanri, Quarry, Pepsi atawọn adugbo kaakiri Abẹokuta ni wọn wa Fathia de, ṣugbọn wọn ko ri i.
Igba to di ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni wọn ri oku ẹ laduugbo Ori Yanrin kan naa, bi Fathia, ọmọleewe Abeokuta Girls Grammar School (AGGS), ṣe di oloogbe lojiji ree. Bẹẹ wọn ni iwe kẹwaa lo fẹẹ bọ si nileewe naa.
Igbiyanju wa lati ba Iya Fathia sọrọ ko bọ si i rara, niṣe lawọn abanikẹdun yi i ka, ti wọn ni ko le sọ ohunkohun lasiko yii, nitori akọbi ọmọ lo bọ sọnu lọwọ rẹ yii, ibanujẹ alailẹgbẹ ni.