Awọn akẹkọọ poli to pa ọga olotẹẹli Water View, n’llọrin, ti dero ẹwọn 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majisireeti kan to filu Ilọrin ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ju awọn ọrẹ meji kan ti wọn jingiri ninu ibalopọ eleeyan mẹta tabi ju bẹẹ lọ, ti wọn ṣeku pa Adeniyi Ojo, ọkunrin to ni otẹẹli kan ti wọn n pe ni Water View, to wa lagbegbe GRA, niluu Ilọrin, sinu ọgba ẹwọn Òke-Kúrá, titi ti idajọ yoo fi waye lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Tẹ o ba gbagbe, Joy Adama Joseph, ẹni ọdun mejidinlogun, ati ọrẹ ẹ, Davies Ọrẹoluwa Favour, ti jẹwọ lasiko tawọn agbofinro n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe awọn lawọn ṣekupa ọga olotẹẹli Water View ọhun, lẹyin tọwọ tẹ wọn ni Mowe Ibafo, nipinlẹ Ogun, ti wọn sa lọ lẹyin ti wọn huwa buruku yii tan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, lo wọ awọn mejeeji lọ siwaju Onidaajọ Kamson Monisọla, niluu Ilọrin, fẹsun ipaniyan.

Agbẹfọba, Sanni Abdullahi, sọ fun kootu pe awọn afurasi ọdaran mejeeji yii ni wọn ba ọga olotẹẹli Water View lalejo, ti wọn si jọ wọnu yara kan lọ ninu otẹẹli naa, ti wọn si tilẹkun mọri gbọn-in gbọn-in. Nigba to ya ni awọn ọmọbinrin mejeeji yii ṣe bii ẹni to fẹẹ ra ohun mimu ẹlẹri-dodo ninu ọgba wọn, ti wọn si gba ibẹ sa lọ.

O tẹsiwaju pe olugbalejo otẹẹli naa, Abdulsalam Tawakalitu, to fura lọ si ẹnu ọna yara naa lati wo ọga wọn wo, ṣugbọn o ba ilẹkun ni titi pa. Nigba ti wọn kan ilẹkun laimọye igba ti wọn o gbọ ijẹ oloogbe ni wọn ja ilẹkun wọle pẹlu tipatipa, ti wọn si ba oku ọga olotẹẹli naa lori bẹẹdi ti wọn ti de e lokun lọwọ ati ẹsẹ, ti wọn si ti ekisa bọ ọ lẹnu. Lẹyin eyi ni wọn ji foonu rẹ gbe lọ, wọn yọ siimu rẹ kuro, wọn tun gbiyanju lati kowo ninu akaunti rẹ, sugbọn iyẹn n beere OTP lọwọ wọn, eyi ti ko jẹ ki wọn ni aṣeyọri lati kowo rẹ lọ.

Bakan naa lo ni iwadii fihan pe Joy, tun mu awọn ohun ija oloro bii ọbẹ, oogun oloro kodinni lọwọ lati fi kun un loorun, ti Adama si gba nnkan ọmọkunrin ọga naa mu pe oun yoo ge e danu.

Agbẹfọba rọ ile-ẹjọ lati ma ṣe gba beeli awọn afurasi ọdaran mejeeji.

Adajọ Kamson gba ẹbẹ rẹ, o paṣẹ pe ki wọn lọọ sọ awọn afurasi mejeeji sọgba ẹwọn. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply