O ma ṣe o, kọntena ṣubu le mọto akero ati kẹkẹ Marwa mọlẹ, eeyan mẹrin lo ku

Adewale Adeoye

Beeyan ba jori ahun, bo ba ri bi tirela kan to gbe kọntena sẹyin ṣe ṣubu lu mọto akero ati kẹkẹ Marwa mọlẹ, tawọn eeyan mẹrin si ku sinu ijamba ọhun, ti awọn to farapa yannayanna ko lonka, ko si ki tọhun ma kaaanu awọn to kuku ojiji ọhun. Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla yii, loju ọna marosẹ Aba Ikot-Ekepene.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Opobo, ni tirela naa ti n bọ pẹlu ẹru ninu kọntena to wa lẹyin rẹ, bo ṣe de agbegbe Aba Ikot-Ekpene, ni bireeki rẹ feeli, to si n lọọ geerege. Mọto akero Sienna kan ati kẹkẹ Marwa kan to wa niwaju rẹ lo lọọ da a bo, tawọn ero bii mẹrin ti wọn wa ninu mọto ọhun si ku loju-ẹsẹ, nitori pe ojiji ni kọntena ọhun wo lu gbogbo wọn mọlẹ.

Ni kete ti iṣẹlẹ naa ti waye lawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ niluu naa, ‘Federal Road Safety Commission’ (FRSC) ti de si agbegbe ọhun, ti wọn si gbiyanju lati dari ọkọ, ki sunkere-fakẹrẹ ma baa waye nitori ijamba ọhun.

Pẹlu pe awọn mẹrin kan ti ku loju-ẹsẹ, awọn ero to wa nitosi gbiyanju lati yọ awọn kọọkan ti wọn wa labẹ palapala abẹ ọkọ ọhun ti wọn gbagbọ pe wọn ko ti i ku, gbogbo igbiyanju wọn lo ja si pabo nitori pe eru to wa ninu kọntena ọhun pọ ju ohun teeyan le fọwọ gbe soke lọ, eyi lo mu ki awọn araalu naa fa ibinu yọ, nitori lati nnkan bii wakati mẹta ti ijamba ọhun ti waye, awọn ẹṣọ ojupopo yii wọn ko ri mọto to maa waa gbe kọntena ọhun kuro lori awọn to wa labẹ mọto.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lawọn ti gbọ si iṣẹlẹ ọhun, ati pe awọn ẹlẹyinju aanu kan ti gbe gbogbo awọn to fara pa ninu ijamba naa lọ sileewosan aladaani kan to wa lagbegbe naa fun itọju, nigba ti wọn tun ko oku awọn to ba iṣẹlẹ naa rin lọ si mọṣuari kan to wa nileewosan to wa niluu naa.

 

Leave a Reply