Ọkọ Salawa Abẹni fẹyinti lẹnu iṣẹ aṣọbode, eyi loun ti Waka Queen sọ nipa rẹ

Faith Adebọla

Awọn to kọkọ ri ọba orin Waka Queen, Salawa Abẹni, ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, pẹlu ọga kọsitọọmu kan to ṣẹṣẹ fẹyinti lẹnu iṣẹ bayii, Alaaji Rasheed Adahunṣe Atọlagbe, ko mọ rara pe baba naa ni ọkọ obinrin olohun iyọ yii rara.

Iṣesi obinrin olorin ọmọ bibi ilu Ẹpẹ yii ninu fọto ati fidio ti wọn jọ wa lọjọ naa lọhun-un fi han pe inu obinrin naa dun denu, pẹlu iwuri lo si fi n rin ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ọga awọn aṣọbode ọhun. Koda, Salawa wa ninu awọn to dekoreeti baba yii, iyẹn awọn ti wọn fi baaji oye tuntun naa si i lapa. Bẹẹ lo n gbeju gbere, to n rẹrin-in muṣẹ, ti ayọ si han loju rẹ jọjọ.

Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, iya ti ọmọ rẹ naa n ṣe daadaa nidii orin kikọ yii ko sọrọ, bẹẹ ni ko pariwo sita pe ọga awọn kọsitọọmu yii ni ọkọ oun tuntun bayii, ati pe ọdun mẹrin sẹyin ni wọn ti fẹra wọn.

Afi lopin ọsẹ to kọja yii ti ọkunrin naa ṣe ọjọọbi, to si tun fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba. Nibẹ ni Lady Waka Queen gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe Salawa Abẹni ti tu aṣiri ikọkọ naa, ti iya to mọ tifun-tẹdọ orin Waka naa si sọ fun gbogbo araye pe ọkọ oun ni ọkunrin naa, pẹlu bo ṣe ki i, to si ṣadura fun un nita gbangba lasiko ti ayẹyẹ naa n lọ lọwọ. Nibi ti kinni naa si dun mọ obinrin olorin yii de, oni nnkan laa jẹ o ṣe e lo fọrọ naa ṣe pẹlu bo ṣe jẹ pe oun funra ẹ lo kọrin nibi inawo naa.

Lasiko ti obinrin yii wa loju agbo lo ti ni, ‘Mi o ni ọrọ pupọ lati sọ ju ki n dupẹ lọwọ Ọlọrun lọ. Ọrọ kekere ni ma a kan sọ nipa ọkọ mi ti mo nifẹẹ ju lọ. Loootọ lo ti fẹyinti, ṣugbọn ko ti i rẹ ọ. Gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe so awa mejeeji pọ lati bii ọdun mẹrin sẹyin, mo gbadura pe ki ẹmi wa gun, ka si maa ṣe aye wa ninu ọ̀pọ̀.

 ‘‘O ri mi gẹgẹ bii olorin, emi naa si ri ọ gẹgẹ bii ‘oloyinbo’, ṣugbọn ifẹ bori ohun gbogbo, ohun to si da mi loju ni pe mi o ṣi ọ yan gẹgẹ bii ọkọ’’.

Gbogbo awọn to ri ọrọ ti obinrin olorin yii kọ lo n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye ọtun to bẹrẹ si i gbe bayii. Niṣe ni ẹni kan ninu wọn si sọ pe abajọ ti iya yii fi n dan, to si da bii ọmọ tuntun bayii. O ni ẹni to ba ri Alaaja Salawa bayii yoo mọ pe inu rẹ dun, ọkan rẹ balẹ, bẹẹ ni awọ rẹ jẹ jade daadaa, ti iṣesi ati iwa rẹ ko si jọ ọjọ ori to wa rara.

Bẹẹ lawọn mi-in n ba a ṣami si adura to ṣe pe oun ati ọkunrin naa yoo lo ara wọn pẹ laṣẹ Edumare.

Tẹ o ba gbagbe, Lateef Adepọju ti gbogbo eeyan mọ si Leaders Records ni obinrin naa kọkọ fẹ, to si bimọ meji fun un. Lẹyin naa lo fẹ ọga olorin Fuji nni, Kollington Ayinla, ko too pada waa fẹ Alaaji Adahunṣe bayii.

Leave a Reply