Olọrun lo fi Tinubu kẹ Naijiria bii mesayawa, a gbọdọ fara da inira yii – Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe Ọlọrun lo fi Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu kẹ orileede Naijiria, oun si ni mesaya lasiko yii.

Ọba Akanbi ṣalaye pe gbogbo ọmọ orileede yii gbọdọ ni suuru pẹlu ijọba Tinubu, nitori oun mọ pe o jẹ ọlọpọlọ pipe lati mu ere ijọba tiwa-n-tiwa de ọdọ gbogbo araalu.

Ninu atẹjade kan ti Oluwoo fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, lo ti ṣalaye pe loootọ ni inira eto ọrọ aje ti agbaye n doju kọ bayii lagbara, ṣugbọn ọwọ ti Aarẹ Tinubu fi n mu un bayii dara pupọ.

O ni ti gbogbo awọn ọmọ orileede yii ba le fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ, ki wọn si maa gbaruku ti i, adun to maa n gbẹyin ewuro ni ọrọ naa yoo pada yọri si.

Ọba Akanbi ṣalaye pe nnkan ti bajẹ jinna lati ọwọ awọn adari to ti kọja lọ, idi niyi ti Aarẹ yii fi nilo asiko to to lati fi ipilẹ to dara lelẹ fun orileede Naijiria to wu ni lori.

O ke si awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ, awọn lameetọ ilu lati jẹ ki ifẹ Naijiria leke lọkan wọn, ki wọn si maa sọrọ ireti fun awọn iran to n bọ.

Ọba Akanbi sọ siwaju pe itan orileede yii yoo yipada si rere laipẹ, lai jinna, o ni Tinubu ni mesaya ti Ọlọrun ran, oun naa lo si kọkọ gbe igbesẹ akin lati yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu.

O ni ki gbogbo ọmọ orileede yii ranti ileri wọn pe awọn yoo jẹ olotitọ, olododo ati ẹni to ṣe e fọkan tan, ki wọn si fara da inira asiko diẹ yii, nitori pe asiko ayọ ti de tan.

Leave a Reply