Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Inu ibẹru nla lawọn akẹkọọ ileewe gbogbonise tijọba apapọ to wa niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, (Federal Polytechnic Ọffa), paapaa ju lọ ẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ nipa ounjẹ (Food Technology), wa di asiko yii. Eyi ko sẹyin bi awọn agbebọn kan ṣe lọọ ka ọkan ninu awọn akẹkọọ ẹka naa, Omidan Toyin Bamidele, mọ’nu ile ẹ, ti wọn si ṣa a pa sibẹ.
ALAROYE gbọ pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, niṣẹlẹ naa waye, ko si sẹni to ti i le sọ awọn to ṣiṣẹ buruku naa boya awọn adigunjale ni tabi awọn agbanipa ati ohun ti arẹwa ọmọbinrin naa ṣe fun wọn ti wọn fi da ẹmi rẹ legbodo.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileewe ijọba apapọ ọhun, Arabinrin Fọlakẹ Oyinloye, sọ pe loootọ ni wọn ṣa akẹkọọ naa pa, inu yara ẹ gan-an ni wọn si ṣeku pa a si. O ni ko sẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ ki iṣẹlẹ naa too waye, ile rẹ to rẹnti to n gbe ni wọn pa a si, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
O ni, ‘‘Titi di asiko yii, a ko mọ idi ti wọn fi pa akẹkọọ naa, bakan naa ni ko sẹni to mọ awọn to ṣiṣẹ ọhun, ṣugbọn nnkan ta a le fidi ẹ mulẹ ni pe wọn ṣa pa a ni.’’
Awọn alaṣẹ ileewe atawọn ẹṣọ alaabo ti n ṣiṣẹ papọ lati wa awọn amookun ṣika naa lawaari, ti wọn aa si foju wina ofin tọwọ ba tẹ wọn.”
Oyinloye juwe iku akẹkọọ naa bii eyi to gbomi loju ẹni, to si ba ni lọkan jẹ. O ni ati adanu nla lo jẹ fun gbogbo awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ Ọffa Poli.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun ṣe iku niṣinmi fun un, ko si rọ mọlẹbi rẹ loju lati fara ki gba adanwo ti iku rẹ mu wa.