Faith Adebọla
Ọrọ ta a pe lọwe ti n laro ninu fun awọn akanda ẹda ti wọn n tọrọ baara nipinlẹ Eko, pẹlu bi Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ṣe bẹrẹ igbesẹ kiko awọn ‘baabiala’ kuro ni gbogbo agbegbe Eko. Ni bayii, awọn onibaara bii aadọta lọwọ ba, ti wọn si ti palẹ wọn mọ kuro nibi ti wọn ti n tọrọ owo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla yii.
Kọmiṣanna ẹka to n ri sọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke awujọ, Mobọlaji Ogunlende, lo lewaju ikọ afaṣẹ-ọba-mu-ni kan ninu eto ti wọn pe ni ‘Special Rescue Operations’.
Lati irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni awọn ikọ yii ti n lọ kaakiri gbogbo oju popo, kọrọ atawọn ileetaja igbalode tawọn onibaara saaba maa n duro si lati tọrọ owo, bi wọn si ṣe n foju kan wọn ni wọn n he wọn bii ẹni he igbin sinu ọkọ akẹru gogoro kan ti wọn gbe wa.
Bo tilẹ jẹ pe ko fi bẹẹ ṣee ṣe fawọn akanda ẹda naa lati sa lọ, tabi jajabọ lọwọ awọn oṣiṣẹ amuni-fọba naa nitori ipo ailera wọn, sibẹ, niṣe lawọn oṣiṣẹ naa n gbe awọn mi-in janto, tabi ki wọn wa kẹkẹ arọ wọn wọnu mọto ọhun, ti ẹlomi-in ninu awọn onibaara ọhun si n sunkun yọbọ bi wọn ṣe n palẹ wọn mọ.
Ẹ oo ranti pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla yii, nileegbimọ aṣofin Eko fi aidunnu wọn han si bawọn alagbe ati akanda ẹda ṣe sọ ọpọ agbegbe ilu Eko di ojuko baara ti wọn ti n tọrọ owo, wọn ni eyi tabuku ipinlẹ naa, wọn si paṣẹ pe kijọba Eko wa nnkan ṣe lati fopin si aṣa radarada naa.
Bakan naa ni Kọmiṣanna Ogunlende sọ fawọn oniroyin kan pe titọrọ baara, tabi lilo awọn majeṣin lati tọrọ owo ko ba aṣa ati ẹsin wa mu, bẹẹ ni iwa ọhun ta ko eto idagbasoke ilu, ati ipinlẹ eyikeyii. Ohun to tiẹ waa buru ju nibẹ ni pe iwadii ti fidi ẹ mulẹ pe awọn kan lara awọn taraalu ro pe alagbe ni wọn yii, niṣe ni wọn kan n fi baara titọrọ boju lati huwa ọdaran.
O ni, “Ijọba ipinlẹ Kano, Kaduna atawọn ipinlẹ mi-in gbogbo ti fofin de gbigbegba baara lawọn ipinlẹ wọn, bawo ni ti Eko ṣe waa jẹ? A rọ ẹnikẹni to ba fẹẹ fawọn onibaara lowo, tabi to fẹẹ ṣetọrẹ aanu lati mu owo tabi ẹbun rẹ lọ sawọn ile atawọn ibudo ta a ya sọtọ lati maa tọju awọn akanda ẹda wọnyi.” Gẹgẹ bo ṣe wi.