Ẹ gba mi o, ọkọ mi gerun ori mi, o fẹẹ fi ṣoogun– Mariam 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

‘‘Ẹni ta a fẹẹ sun jẹ tẹlẹ to tun n fepo para lọrọ ọkọ mi, latigba ti mo ti ni mi o nifẹẹ rẹ mọ lo ti n wa gbogbo ọna lati ṣe aburu fun mi, o tun wa lọọ ge lara irun mi lati fi ṣe oogun’’. Orin yii lo gbẹnu iyaale ile kan, Mariam Ọlatunji, nigba to n rawọ ẹbẹ sawọn adajọ kootu kọkọ-kọkọ to wọ ọkọ rẹ, Abdulrazaq Jamiu, lọ pe ki wọn tu igbeyawo awọn ka, oun ko ṣe mọ. O ni ọkunrin naa ti fẹẹ gba ẹmi oun, kọrọ aye si ya ju kọrọ ọrun lọ.

Kootu kọkọ-kọkọ kan ti wọn n pe ni Area-Court, to fikalẹ ṣagbegbe Centre-Igboro, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni awọn tọkọ-taya meji yii wọra wọn lọ.

Olupẹjọ naa, Mariam Ọlatunji, rojọ niwaju adajọ pe latigba toun ti sọ pe ifẹ ọkunrin naa ti yọ lẹmi-in oun lo ti bẹrẹ si i wa gbogbo ọna lati saburu soun, to si n dunkooko mọ ẹmi oun debii pe o tun lọọ ge lara irun oun.

Mariam ni oun ko nifẹẹ rẹ mọ rara, kọda, oun pẹlu ọkọ oun ko le duro sọrọ fun iṣẹju kan mọ nibi toun koriira rẹ de, ṣugbọn ki ile-ẹjọ too tu igbeyawo naa ka, ki wọn kọkọ ba oun gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira (80,000), ti Abdulrazaq ti i ṣe ọkọ oun jẹ oun. O tẹsiwaju pe oun ya ọkọ oun lowo naa lati fi ra ilẹ ni, ṣugbọn ko da a pada foun mọ.

Olujẹjọ to jẹ ọkọ Mariam, Abdulrazaq Jamiu, sọ fun adajọ pe oun naa ṣetan lati kọ Mariam silẹ gẹgẹ bii ohun to beere fun, ṣugbọn oun ko jẹ ẹ lowo kankan, irọ to jinna soootọ ni pe oun jẹ ẹ lowo.

Onidaajọ Abdulkadir Ahmed, tu igbeyawo naa ka pẹlu ilana adehun ti wọn ṣe fun’ra wọn nibaamu pẹlu ilana ẹṣin Musulumi.

Adajọ sọ fun Abilekọ Mariam pe o gbọdọ ṣe nnkan oṣu lẹẹmẹta ko too le ni anfaani lati fẹ ọkọ miiran. Eyi tumọ si pe lẹyin oṣu mẹta ti wọn kọ ara wọn silẹ ni yoo to le fẹ ọkọ miiran.

Leave a Reply