Eyi nidi ti mo fi fẹran lati maa ṣira mi silẹ-Zainab

Faith Adebọla

 Bakare Zainab, arẹwa oṣere-binrin onitiata to niwaju ati akọyinsi daadaa nni, ti ṣalaye nipa idi to fi saaba maa n ya awọn fọto ati fidio arimaleelọ, nibi to ti maa n ṣira silẹ, tawọn ololufẹ rẹ si maa n jẹ dodo ẹwa ati oge rẹ.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii pẹlu iwe iroyin City People, apọnbeporẹ yii ni ki i ṣe pe oun kan maa n ṣira silẹ bẹẹ naa, amọ nitori oun fẹran lati maa wọ aṣọ to ba tẹ oun lọrun, to si le mu k’oun rin, koun yan fanda boun ṣe fẹ, lo mu kawọn eeyan maa ri oun bi wọn ṣe n ri oun yẹn. Ati pe, ni toun o, oun ki i wo aago alaago ṣiṣẹ, eyi wu mi ko wu ọ si lọrọ ile aye, bo ṣe rọ oun lọrun, to si tẹ oun lọrun, leyii toun n ṣe wọnyẹn.

Zainab ni: “Ohun to ba rọ mi lọrun lati wọ, to si tẹ mi lọrun, ni mo maa n wọ. Eleyii ki i ṣe ọrọ pe mo wulẹ fẹẹ patẹ ara mi. Imura ki i ṣe ọrọ nnkan tawọn eeyan maa maa ro nipa rẹ, ọrọ nnkan to ba tẹ iwọ alara lọrun ni. Oju ọjọ Naijiria ko daa, ilẹ olooru la wa, ọpọ igba looru maa n mu, igba mi-in si maa n daa fun mi.

“Lero temi, ko kan aye bi mo ṣe mura, ko kan ẹnikan. Agbalagba ni mi. Mo ti dọmọ ọdun marundinlogoji bayii, aa, ootọ ma ni! Awọn ojugba mi kan ti bimọ nile ọkọ wọn.”

Zainab tun sọ pe oun ko fẹ kawọn ololufẹ oun maa foju ọmọ buruku wo oun tori oun ṣi’ra silẹ, o ni ọna to mu k’oun lominira ni, koun si maa gbatẹgun sawọn ẹya-ara oun, ki i ṣe pe oun fẹẹ polowo idi tabi ọyan.

Amọ alaye ti oṣere-binrin yii ṣe ko tẹ awọn kan lọrun lara awọn ololufẹ rẹ, bawọn kan ṣe n sọ pe isọkusọ ọrọ lo n sọ lẹnu, ti wọn n sọ pe ba a ṣe ri la a ko ni, ati pe imura ọmọluabi gbọdọ ba awujọ mu, bẹẹ lawọn kan lara awọn ololufẹ rẹ n sọ pe laye ode oni, imura ki i ṣe ọrọ ohun tawọn eeyan n sọ, konko jabele ni, kaluku lo n ṣe tiẹ, wọn ni kawọn eeyan yee tẹmbẹlu ọmọ Bakare, iran odidẹrẹ ni i re’ra o.

Leave a Reply