Eyi lohun to ṣẹlẹ si Bọlanle Ninalowo niluu Ikorodu

Jọkẹ Amọri

 Owe Yoruba kan lo sọ pe ọmọ ẹni ki i ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ si ti ọmọ ẹlomi-in. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu arẹwa oṣere ọkunrin ti gbogbo awọn obinrin fẹran daadaa nni, Bọlanle Ninalowo, ti gbogbo eeyan tun maa n pe ni Makanaki, pẹlu bo ṣe pada si ilu abinibi rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ ‘Ọga Day’, nibi ti ọba ilu naa, Ayẹngburẹn tilu Ikorodu, Ọba Kabiru Adewale Shotobi, ti fi ami-ẹyẹ da a lọla fun ipa ribiribi to n ko lati gbe ilu Ikorodu to ti wa ga ati bo ṣe jẹ awokọṣe pataki lawujọ.

Pẹlu idunnu ni Ọba Ikorodu fi ki Ninalowo kaabọ si gbọngan ayẹyẹ ti eto naa ti waye. Bi oṣerekunrin to duro nilẹ daadaa naa ṣe dewaju kabiyesi lo dọbalẹ gbalaja lati ki ọba alade naa. Tẹrin-tọyaya ni Kabiyesi naa fi ki oṣere yii saarin wọn, bẹẹ lọba alade yii n ju irukẹrẹ soke lati ki i.

Lẹyin eyi ni Ayẹgbunren bẹrẹ si i rọjo adura le Ninalowo lori, ko too waa gbe ami-ẹyẹ ọkunrin takuntakun to tun jẹ awokọṣẹ to jẹ ọmọ bibi ilu Ikorodu yii le e lọwọ.

Ninalowo paapaa ko le pa idunnu rẹ mọra lasiko to gba ami-ẹyẹ yii, oju-ẹsẹ lo ti gbe fọto ibi ti wọn ti n da a lọla naa si ori Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ bayii pe, ‘‘Inu mi dun si atilẹyin ati ifẹ ti mo ri gba lati ilu abinibi mi. O jẹ ohun iwuri fun mi pe awọn eeyan Ikorodu mọ riri mi, ti wọn si buyi fun mi, labẹ idari Ọba wa, Kabiru Adewale Shotobi, Ayangbunrẹn ilu Ikorodu. Ki Ọlọrun bukun fun gbogbo ọmọ Ikorodu patapata. Ikorodu ọga, ilu ti ko si alabaaru. Maka, ọmọ Ẹluku Mẹdẹ’’.

Bi oṣere yii ṣe gbe fidio naa sori ikanni rẹ ni awọn tiẹ ti n ki i ku oriire, iyalẹnu lo si jẹ fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ nitori pe wọn ko mọ pe ọmọ bibi ilu Ikorodu ni oṣere naa.

Ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ ni wọn ki i, ti awọn ọmọ bibi ilu Ikorodu naa si n ki i kaabọ pada sile.

Leave a Reply