Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọjọ ibanujẹ, eyi to kun fun ẹkun ati ipayinkeke lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, ọṣẹ Kọkanla, ọdun 2023 yii, jẹ fawọn olugbe adugbo Idi-Iṣin, n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, pẹlu bi wọn ṣe deede ba oku ọkan ninu wọn, Abilekọ Ọlaitan Gbenle, ninu ile ẹ ti wọn so o lọwọ atẹsẹ si, to si ti kọja sọrun alakeji. Awọn olubi ẹda kan lo lọọ ka a mọle lai ro tẹlẹ, ti wọn de e lọwọ-lẹsẹ, ti wọn si fun un lọrun pa ki wọn too ji awọn nnkan ini ẹ kan. Lẹyin ti wọn ṣiṣẹ buruku wọn yii tan ni wọn sa lọ raurau.
Iku buruku ni wọn fi pa Abilekọ Gbenle, ẹni to ti figba kan jẹ akọwe agba lẹnu iṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ. Wọn ni ko si oju ọgbẹ tabi àpá kankan lara oku iya naa. Eyi lo si jẹ ki awọn eeyan gba pe niṣe lawọn alejo ọran to gba lọjọ ta a wi yii fun un lọrun pa ni.
Ọkọ ayọkẹlẹ mejeeji ti oloogbe ni nigba to wa laye lawọn apaayan naa gbe lọ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ rẹ mejeeji ati kaadi teeyan fi n gbowo lẹnu ẹro ipọwo (ATM).
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii, olugbe adugbo ọhun kan woye pe, “o ṣee ṣe ko jẹ pe nigba ti iya ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin (69) naa n gbiyanju lati wa ọkọ wọnu ile lawọn ẹruuku naa tẹle e wọle, tabi ko jẹ pe
lasiko ti ko si nile ni wọn ti fo fẹnsi wọ inu ọgba naa, ti wọn si duro de e titi to fi de.
“Idi ni pe aṣọ ti mama wọ jade lọjọ yẹn lo ṣi wa lọrun wọn nibi ti wọn pa wọn sI”.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, laipẹ yii lọga ninu awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri yii kegbajare sita pe awọn kan n lepa ẹmi oun.
Wọn ni ede aiyede kan lo wa laarin Abilekọ Gbenle atawọn ọmọ iṣọta kan laduugbo to kọle si pẹlu bi wọn ṣe maa mugbo laduugbo ọhun ni gbogbo igba, to kilọ fun wọn pe ki wọn jawọ ninu iwa naa, ṣugbọn ti awọn tọọgi wọnyi sọ ọrọ naa di wahala mọ ọn lọwọ.
A gbọ pe ọmọbirin kan ṣoṣo ti oloogbe fi saye lọ ko si nitosi lasiko iṣẹlẹ naa.